Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú: Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni. Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko, àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu. Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun, yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò. Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, Ìwọ ìlú! Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia! Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá, kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn. Kí ni ìdáhùn tí a ó fún agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà? “OLúWA ti fi ìdí Sioni kalẹ̀, àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”
Kà Isaiah 14
Feti si Isaiah 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isaiah 14:28-32
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò