Li ọdun ti Ahasi ọba kú, li ọ̀rọ-imọ yi wà. Iwọ máṣe yọ̀, gbogbo Filistia, nitori paṣan ẹniti o nà ọ ṣẹ́; nitori lati inu gbòngbo ejo ni pãmọlẹ kan yio jade wá, irú rẹ̀ yio si jẹ́ ejò iná ti nfò. Akọbi awọn otòṣi yio si jẹ, awọn alaini yio si dubulẹ lailewu; emi o si fi iyàn pa gbòngbo rẹ, on o si pa iyokù rẹ. Hu, iwọ ẹnu-odi; kigbe, iwọ ilu; gbogbo Palestina, iwọ ti di yiyọ́: nitori ẹ̃fin yio ti ariwa jade wá, ẹnikan kì yio si yà ara rẹ̀ kuro lọdọ ẹgbẹ́ rẹ̀. Èsi wo li a o fi fun awọn ikọ̀ orilẹ-ède? Pe, Oluwa ti tẹ̀ Sioni dó, talaka ninu awọn enia rẹ̀ yio si sá wọ̀ inu rẹ̀.
Kà Isa 14
Feti si Isa 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isa 14:28-32
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò