Hosea 2:16-20

Hosea 2:16-20 YCB

“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, Ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’; Ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’ ni OLúWA wí. Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀; ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́ Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀. Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́ Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé. Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́ ìwọ yóò sì mọ OLúWA.