Hosea 2

2
1“Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘àyànfẹ́ mi.’
Ẹ̀sùn tí a fi kan ìyàwó aláìṣòótọ́
2“Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí,
nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi,
Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.
Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀
àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.
3Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò
Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i.
Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀,
Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀
Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́.
4Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀
nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́
5Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè,
ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú.
Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn,
tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,
ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi,
òróró mi àti ohun mímu mi.’
6Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà
Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.
7Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn;
Yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn.
Nígbà náà ni yóò sọ pé,
‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́
nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’
8Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni
àti ẹni tó fún un ní ọkà,
ọtí wáìnì tuntun àti òróró
ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Baali.
9“Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n,
èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀.
Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà
ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀.
10Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn
lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀
kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi
11Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin:
àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀,
ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn.
12Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run,
èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀,
Èmi yóò sọ wọ́n di igbó,
àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.
13Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀
nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali;
tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,
tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ.
Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,”
ni Olúwa wí.
14“Nítorí náà, èmi yóò tàn án
Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀
Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀
15Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,
Èmi yóò fi Àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un.
Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti.
16“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,
Ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’;
Ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’
ni Olúwa wí.
17Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀;
ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́
18Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú
fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti
àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀.
Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́
Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà
kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.
19Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé.
Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti
òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.
20Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́
ìwọ yóò sì mọ Olúwa.
21“Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà”
ni Olúwa wí.
“Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn
àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;
22Ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà,
wáìnì tuntun àti òróró lóhùn
Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn.
23Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà
Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘àánú Gbà.’
Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’
‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Hosea 2: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀