Hosea 1:9-10

Hosea 1:9-10 YCB

OLúWA sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín. “Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli yóò pọ̀ bí i iyanrìn etí Òkun tí a kò le wọ́n, tí a kò sì le è kà, yóò sì ṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’