Hos 1:9-10

Hos 1:9-10 YBCV

Nigbana ni Ọlọrun wipe, Pè orukọ rẹ̀ ni Loammi; nitori ẹnyin kì iṣe enia mi, emi kì yio si ṣe Ọlọrun nyin. Ṣugbọn iye awọn ọmọ Israeli yio ri bi iyanrìn okun, ti a kò le wọ̀n ti a kò si lè ikà; yio si ṣe, ni ibi ti a gbe ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, ibẹ̀ li a o gbe wi fun wọn pe, Ẹnyin li ọmọ Ọlọrun alãyè.