Heberu 5:7-10

Heberu 5:7-10 YCB

Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀. Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀; Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ tirẹ̀: Tí a yàn ní olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melkisedeki.