Heb 5:7-10

Heb 5:7-10 YBCV

Ẹni nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o si bẹ̀bẹ lọdọ ẹniti o le gbà a silẹ lọwọ ikú, a si gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ rẹ̀, Bi o ti jẹ Ọmọ nì, sibẹ o kọ́ igbọran nipa ohun ti o jìya; Bi a si ti sọ ọ di pipé, o wá di orisun igbala ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o ngbọ́ tirẹ̀: Ti a yàn li Olori Alufa lati ọdọ Ọlọrun wá nipa ẹsẹ Melkisedeki.