Gẹnẹsisi 41:1-16

Gẹnẹsisi 41:1-16 YCB

Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Farao lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Naili. Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko. Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Naili, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà. Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Farao jí. Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn: ó rí síírí ọkà méje tí ó kún, ó yómọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo. Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yómọ, afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù. Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yómọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Farao jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni. Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Ejibiti. Farao rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtumọ̀ àlá náà fún un. Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Farao pé, “Lónìí ni mo rántí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nígbà kan tí Farao bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lá àlá, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. Ọmọkùnrin ará Heberu kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. A rọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtumọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un. Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí. A dá mi padà sí ipò mi, a sì so ọkùnrin kejì kọ́ sórí ọ̀wọ̀n.” Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Josẹfu, wọn sì mú un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá síwájú Farao. Farao wí fún Josẹfu, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.”