Gẹn 41:1-16

Gẹn 41:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

O SI ṣe li opin ọdún meji ṣanṣan, ni Farao lá alá: si kiyesi i, o duro li ẹba odo. Si kiyesi i abo-malu meje, ti o dara ni wiwò, ti o sanra, jade lati inu odò na wá: nwọn si njẹ ninu ẽsu-odò. Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o buru ni wiwò, ti o si rù, jade lẹhin wọn lati inu odò na wá; nwọn si duro tì awọn abo-malu nì ni bèbe odò na. Awọn abo-malu ti o buru ni wiwò ti o si rù si mú awọn abo-malu meje ti o dara ni wiwò ti o si sanra wọnni jẹ. Bẹ̃ni Farao jí. O si sùn, o si lá alá lẹrinkeji: si kiyesi i, ṣiri ọkà meje yọ lara igi ọkà kan, ti o kún ti o si dara. Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje ti o fori, ti afẹfẹ íla-õrùn rẹ̀ dànu si rú jade lẹhin wọn. Ṣiri meje ti o fori si mú ṣiri meje daradara ti o kún nì jẹ. Farao si jí, si kiyesi i, alá ni. O si ṣe li owurọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò lelẹ; o si ranṣẹ o si pè gbogbo awọn amoye Egipti, ati gbogbo awọn ọ̀mọran ibẹ̀ wá: Farao si rọ́ alá rẹ̀ fun wọn: ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o le tumọ wọn fun Farao. Nigbana li olori agbọti wi fun Farao pe, Emi ranti ẹ̀ṣẹ mi loni: Farao binu si awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si fi mi sinu túbu ni ile-túbu olori ẹṣọ́, emi ati olori alasè: Awa si lá alá li oru kanna, emi ati on; awa lá alá olukuluku bi itumọ̀ alá tirẹ̀. Ọdọmọkunrin kan ara Heberu, ọmọ-ọdọ olori ẹṣọ́, si wà nibẹ̀ pẹlu wa; awa si rọ́ wọn fun u, o si tumọ̀ alá wa fun wa, o tumọ̀ fun olukuluku gẹgẹ bi alá tirẹ̀. O si ṣe bi o ti tumọ̀ fun wa, bẹ̃li o si ri; emi li o mú pada si ipò iṣẹ mi, on li o si sorọ̀. Nigbana ni Farao ranṣẹ o si pè Josefu, nwọn si yara mú u jade kuro ninu ihò-túbu; o si fari rẹ̀, o si parọ̀ aṣọ rẹ̀, o si tọ̀ Farao wá. Farao sí wi fun Josefu pe, Emi lá alá, kò si si ẹnikan ti o le tumọ̀ rẹ̀: emi si gburó rẹ pe, bi iwọ ba gbọ́ alá, iwọ le tumọ̀ rẹ̀. Josefu si da Farao li ohùn pe, Ki iṣe emi: Ọlọrun ni yio fi idahùn alafia fun Farao.

Gẹn 41:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn ọdún meji gbáko, Farao náà wá lá àlá pé òun dúró létí odò Naili. Ó rí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọ́n sì ń dán, wọ́n ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò. Rírí tí yóo tún rí, ó rí àwọn mààlúù meje mìíràn, wọ́n tún ti inú odò náà jáde wá, àwọn wọnyi rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn meje ti àkọ́kọ́. Àwọn meje tí wọ́n rù hangangan náà ki àwọn meje tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ mọ́lẹ̀, wọ́n sì gbé wọn mì, Farao bá tají. Ó tún sùn, ó sì lá àlá mìíràn, rírí tí yóo tún rí, ó rí ṣiiri ọkà meje lórí ẹyọ igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ. Ó sì tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára. Àwọn ṣiiri ọkà tínínrín meje náà gbé àwọn meje tí wọ́n yọmọ mì. Farao bá tún tají, ó sì tún rí i pé àlá ni òun ń lá. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú bá Farao, ó bá ranṣẹ lọ pe gbogbo àwọn adáhunṣe ati àwọn amòye ilẹ̀ Ijipti, ó rọ́ àlá náà fún wọn, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó lè túmọ̀ rẹ̀ fún un. Nígbà náà ni agbọ́tí sọ fún Farao pé, “Mo ranti ẹ̀ṣẹ̀ mi lónìí. Nígbà tí inú fi bí ọba sí àwa iranṣẹ rẹ̀ meji, tí ọba sì gbé èmi ati alásè jù sẹ́wọ̀n ní ilé olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin, àwa mejeeji lá àlá ní òru ọjọ́ kan náà, olukuluku àlá tí a lá ni ó sì ní ìtumọ̀. Ọdọmọkunrin Heberu kan wà níbẹ̀ pẹlu wa, ó jẹ́ iranṣẹ olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin, nígbà tí a rọ́ àlá wa fún un, ó túmọ̀ wọn fún wa. Bí olukuluku wa ti lá àlá tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ó túmọ̀ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ó ti túmọ̀ àlá wa, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó sì rí. Ọba dá mi pada sí ààyè mi, ó sì pàṣẹ kí wọ́n so alásè kọ́.” Farao bá ranṣẹ lọ pe Josẹfu, wọ́n sì mú un jáde kúrò ninu ẹ̀wọ̀n kíá. Lẹ́yìn tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá siwaju Farao. Farao sọ fún un pé, “Mo lá àlá kan, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè túmọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá sọ fún mi pé, bí o bá gbọ́ àlá, o óo lè túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá Farao lóhùn, ó ní, “Kò sí ní ìkáwọ́ mi, Ọlọrun ni yóo fún kabiyesi ní ìdáhùn rere.”

Gẹn 41:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Farao lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Naili. Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko. Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Naili, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà. Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Farao jí. Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn: ó rí síírí ọkà méje tí ó kún, ó yómọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo. Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yómọ, afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù. Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yómọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Farao jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni. Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Ejibiti. Farao rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtumọ̀ àlá náà fún un. Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Farao pé, “Lónìí ni mo rántí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nígbà kan tí Farao bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lá àlá, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. Ọmọkùnrin ará Heberu kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. A rọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtumọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un. Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí. A dá mi padà sí ipò mi, a sì so ọkùnrin kejì kọ́ sórí ọ̀wọ̀n.” Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Josẹfu, wọn sì mú un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá síwájú Farao. Farao wí fún Josẹfu, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.”