Jakọbu sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà-oòrùn. Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi. Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọpọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà.
Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?”
Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.”
Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ ọmọ Nahori?”
Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.”
Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?”
Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.”
Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì ṣú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.”
Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakeli dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà. Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi. Jakọbu sì fẹnu ko Rakeli ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. Jakọbu sì wí fún Rakeli pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rebeka. Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀.
Ní kété tí Labani gbúròó Jakọbu ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jakọbu, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nígbà náà ni Jakọbu ròyìn ohun gbogbo fún un. Labani sì wí pé, “Ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.”