Gẹn 29:1-14

Gẹn 29:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Jakọbu sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò rẹ̀, ó sì dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà-oòrùn. Ó sì rí kànga kan ní pápá, agbo àgùntàn mẹ́ta sì dúró láti mu omi ní ibi kànga náà, nítorí pé láti inú kànga náà ni wọ́n ti ń fi omi fún agbo àgùntàn. Òkúta tí a gbé dí ẹnu kànga náà sì tóbi gidigidi. Nígbà tí gbogbo agbo ẹran bá péjọpọ̀ sí ibẹ̀ tán ni àwọn darandaran yóò tó yí òkúta náà kúrò, tí wọn yóò sì fún àwọn ẹran náà ní omi, tí wọ́n bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ tán, wọn yóò tún yí òkúta náà padà sí ẹnu kànga náà. Jakọbu béèrè lọ́wọ́ àwọn darandaran náà pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi níbo ni ẹ̀yin ti wá?” Àwọn náà sì dáhùn pé, “Láti Harani ni.” Ó sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ ọmọ Nahori?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa mọ̀ ọ́n.” Jakọbu béèrè pé, “Ṣe àlàáfíà ni ó wà?” Wọ́n sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni. Wò ó, Rakeli ọmọ rẹ̀ ni ó ń bọ̀ yìí pẹ̀lú agbo àgùntàn.” Ó sì wí pé, “Kíyèsi, ilẹ̀ ò tí ì ṣú, kò tì í tó àkókò fún àwọn ohun ọ̀sìn láti wọ̀. Ẹ fún àwọn ẹran wọ̀nyí ní omi, kí ẹ ba à le tètè dà wọ́n padà láti jẹun.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.” Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakeli dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà. Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi. Jakọbu sì fẹnu ko Rakeli ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. Jakọbu sì wí fún Rakeli pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rebeka. Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀. Ní kété tí Labani gbúròó Jakọbu ọmọ arábìnrin rẹ̀, ó jáde lọ pàdé Jakọbu, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì mú un lọ sí ilé. Nígbà náà ni Jakọbu ròyìn ohun gbogbo fún un. Labani sì wí pé, “Ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ ara mi ni ìwọ jẹ́.”

Gẹn 29:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Jakọbu tún ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, nígbà tí ó ṣe, ó dé ilẹ̀ àwọn ará ìlà oòrùn. Bí ó ti gbójú sókè, ó rí kànga kan ninu pápá, ati agbo aguntan mẹta tí wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, nítorí pé láti inú kànga yìí ni wọ́n ti ń fún àwọn aguntan náà ní omi mu. Òkúta tí wọ́n sì yí dí ẹnu kànga náà tóbi pupọ. Nígbà tí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá da aguntan wọn dé ìdí kànga yìí ni wọ́n tó ń yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga. Lẹ́yìn náà, wọn á fún àwọn aguntan wọ́n lómi mu, wọ́n á sì yí òkúta náà pada sẹ́nu kànga. Jakọbu bá bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ̀yin arakunrin mi, níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Harani ni.” Ó tún bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ Labani ọmọ Nahori?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A mọ̀ ọ́n.” Ó tún bi wọ́n pé, “Ṣé alaafia ni ó wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, wò ó, Rakẹli, ọmọbinrin rẹ̀, ni ó ń da aguntan bọ̀ ní ọ̀kánkán yìí.” Jakọbu sọ pé, “Oòrùn ṣì wà lókè, kò tíì tó àkókò láti kó àwọn ẹran jọ sójú kan, ẹ tètè fún àwọn aguntan ní omi mu, kí ẹ sì dà wọ́n pada lọ jẹ koríko sí i.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò ṣeéṣe, àfi bí gbogbo àwọn olùṣọ́-aguntan bá dé tán, tí a bá yí òkúta kúrò lórí kànga, nígbà náà ni a tó lè fún àwọn aguntan ní omi mu.” Bí ó ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakẹli dé pẹlu agbo aguntan baba rẹ̀, nítorí pé òun ni ó ń tọ́jú wọn. Nígbà tí Jakọbu rí Rakẹli, ọmọ Labani, tíí ṣe arakunrin ìyá rẹ̀, ati agbo aguntan Labani, ó yí òkúta náà kúrò lẹ́nu kànga, ó sì pọn omi fún wọn. Jakọbu bá fi ẹnu ko Rakẹli lẹ́nu, ó sì bú sẹ́kún. Ó sọ fún Rakẹli pé, ìbátan baba rẹ̀ ni òun jẹ́, ati pé ọmọ Rebeka ni òun. Rakẹli bá sáré lọ sọ fún baba rẹ̀. Nígbà tí Labani gbọ́ ìròyìn ayọ̀ náà pé, Jakọbu ọmọ arabinrin òun dé, ó sáré lọ pàdé rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, ó sì mú un wá sí ilé. Jakọbu ròyìn ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ fún Labani. Labani bá dá a lọ́kàn le, ó ní, “Láìsí àní àní, ẹ̀jẹ̀ kan náà ni wá” Jakọbu sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún oṣù kan.

Gẹn 29:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

JAKOBU si mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n, o si wá si ilẹ awọn ara ìla-õrùn. O si wò, si kiyesi i, kanga kan ninu oko, si kiyesi i, agbo-agutan mẹta dubulẹ tì i; nitori pe, lati inu kanga na wá ni nwọn ti nfi omi fun awọn agbo-agutan: okuta nla si wà li ẹnu kanga na. Nibẹ̀ ni gbogbo awọn agbo-ẹran kojọ pọ̀ si: nwọn si fun awọn agutan li omi, nwọn si tun yí okuta dí ẹnu kanga si ipò rẹ̀. Jakobu si bi wọn pe, Ẹnyin arakunrin mi, nibo li ẹnyin ti wá? nwọn si wipe, lati Harani li a ti wá. O si bi wọn pe, ẹnyin mọ̀ Labani, ọmọ Nahori? Nwọn si wipe, Awa mọ̀ ọ. O si bi wọn pe, Alafia ki o wà bi? nwọn si wipe Alafia ni; si kiyesi i, Rakeli, ọmọbinrin rẹ̀ mbọ̀wá pẹlu ọwọ́-ẹran. O si wipe, Kiyesi i, ọjọ́ mbẹ sibẹ̀, bẹ̃ni kò tó akokò ti awọn ẹran yio wọjọ pọ̀: ẹ fun awọn agutan li omi, ki ẹ si lọ ibọ́ wọn. Nwọn si wipe, Awa kò le ṣe e, titi gbogbo awọn agbo-ẹran yio fi wọjọ pọ̀, ti nwọn o si fi yí okuta kuro li ẹnu kanga; nigbana li a le fun awọn agutan li omi. Nigbati o si mba wọn sọ̀rọ lọwọ, Rakeli de pẹlu awọn agutan baba rẹ̀: on li o sa nṣọ́ wọn. O si ṣe, nigbati Jakobu ri Rakeli, ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ̀, ati agutan Labani, arakunrin iya rẹ̀, ni Jakobu si sunmọ ibẹ̀, o si yí okuta kuro li ẹnu kanga, o si fi omi fun gbogbo agbo-ẹran Labani, arakunrin iya rẹ̀. Jakobu si fi ẹnu kò Rakeli li ẹnu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o sọkun. Jakobu si wi fun Rakeli pe arakunrin baba rẹ̀ li on, ati pe, ọmọ Rebeka li on: ọmọbinrin na si sure o si sọ fun baba rẹ̀. O si ṣe ti Labani gburó Jakobu, ọmọ arabinrin rẹ̀, o sure lọ ipade rẹ̀, o si gbá a mú, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si mu u wá si ile rẹ̀. On si ròhin gbogbo nkan wọnni fun Labani. Labani si wi fun u pe, egungun on ẹran-ara mi ni iwọ iṣe nitõtọ. O si bá a joko ni ìwọn oṣù kan.