Eksodu 24:12-18

Eksodu 24:12-18 YCB

OLúWA sì sọ fún Mose pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhìn-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní wàláà òkúta pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.” Nígbà náà ni Mose jáde lọ pẹ̀lú Joṣua arákùnrin rẹ̀. Mose lọ sí orí òkè Ọlọ́run. Ó sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsi i, Aaroni àti Huri ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnìkan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ. Nígbà tí Mose gun orí òkè lọ, ìkùùkuu bo orí òkè náà. Ògo OLúWA sì wà ní orí òkè Sinai. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni OLúWA kọ sí Mose láti inú ìkùùkuu náà wá. Ni ojú àwọn ọmọ Israẹli ògo OLúWA náà dàbí iná ajónirun ni orí òkè. Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.