Eks 24:12-18
Eks 24:12-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Mose pe, Gòke tọ̀ mi wá sori òke, ki o si duro nibẹ̀; emi o si fi walã okuta fun ọ, ati aṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ, ki iwọ ki o le ma kọ́ wọn. Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun. O si wi fun awọn àgba na pe, Ẹ duro dè wa nihinyi, titi awa o fi tun pada tọ̀ nyin wá: si kiyesi i, Aaroni ati Huri mbẹ pẹlu nyin: bi ẹnikan ba li ọ̀ran kan, ki o tọ̀ wọn wá. Mose si gòke lọ sori òke na, awọsanma si bò òke na mọlẹ. Ogo OLUWA si sọkalẹ sori òke Sinai, awọsanma na si bò o mọlẹ ni ijọ́ mẹfa: ni ijọ́ keje o ké si Mose lati ãrin awọsanma wá. Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israeli. Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.
Eks 24:12-18 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA wí fún Mose pé, “Gun orí òkè tọ̀ mí wá, kí o dúró sibẹ, n óo sì kó wàláà tí wọ́n fi òkúta ṣe fún ọ, tí mo kọ àwọn òfin ati ìlànà sí, fún ìtọ́ni àwọn eniyan yìí.” Mose bá gbéra, òun ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ó gun orí òkè Ọlọrun lọ. Ó sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ẹ dúró níhìn-ín dè wá títí a óo fi pada wá bá yín. Aaroni ati Huri wà pẹlu yín, bí ẹnikẹ́ni bá ní àríyànjiyàn kan, kí ó kó o tọ̀ wọ́n lọ.” Mose bá gun orí òkè náà lọ, ìkùukùu sì bo orí òkè náà. Ògo OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ìkùukùu sì bò ó fún ọjọ́ mẹfa, ní ọjọ́ keje, OLUWA pe Mose láti inú ìkùukùu náà. Lójú àwọn eniyan Israẹli, ìrísí ògo OLUWA lórí òkè náà dàbí iná ńlá tí ń jóni ní àjórun. Mose wọ inú ìkùukùu náà lọ, ó gun orí òkè náà, ó sì wà níbẹ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru.
Eks 24:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
OLúWA sì sọ fún Mose pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhìn-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní wàláà òkúta pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.” Nígbà náà ni Mose jáde lọ pẹ̀lú Joṣua arákùnrin rẹ̀. Mose lọ sí orí òkè Ọlọ́run. Ó sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsi i, Aaroni àti Huri ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnìkan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.” Nígbà tí Mose gun orí òkè lọ, ìkùùkuu bo orí òkè náà. Ògo OLúWA sì wà ní orí òkè Sinai. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni OLúWA kọ sí Mose láti inú ìkùùkuu náà wá. Ni ojú àwọn ọmọ Israẹli ògo OLúWA náà dàbí iná ajónirun ni orí òkè. Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.