Efesu 5:3-14

Efesu 5:3-14 YCB

Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́. Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà, (tí í ṣé abọ̀rìṣà) tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn. Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀: (Nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí. Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé, “Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun, sí jíǹde kúrò nínú òkú Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”