Efe 5:3-14

Efe 5:3-14 Yoruba Bible (YCE)

Kí á má ṣe gbúròó ìwà àgbèrè, tabi oríṣìíríṣìí ìṣekúṣe, tabi ojúkòkòrò láàrin àwọn eniyan Ọlọrun. Ìwà ìtìjú, ọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tabi àwàdà burúkú kò yẹ yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọpẹ́ sí Ọlọrun ni ó yẹ yín. Ẹ̀yin alára mọ̀ dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń ṣe àgbèrè, tabi tí ó ń ṣe ìṣekúṣe, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó ń bọ̀rìṣà, tí yóo ní ìpín ninu ìjọba Kristi, tíí ṣe ìjọba Ọlọrun. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ. Nítorí irú èyí ni ibinu Ọlọrun fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọràn. Nítorí náà ẹ má ṣe fi ara wé wọn. Nítorí nígbà kan, ninu òkùnkùn patapata ni ẹ wà. Ṣugbọn ní àkókò yìí ẹ ti bọ́ sinu ìmọ́lẹ̀ nítorí ẹ ti di ẹni Oluwa. Ẹ máa hùwà bí ọmọ ìmọ́lẹ̀. Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ ni oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere, òdodo ati òtítọ́. Kí ẹ máa wádìí ohun tí yóo wu Oluwa. Ẹ má ṣe bá àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ òkùnkùn tí kò léso rere kẹ́gbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá wọn wí. Nítorí àwọn ohun tí wọn ń ṣe níkọ̀kọ̀ tilẹ̀ ti eniyan lójú láti sọ. Nítorí gbogbo nǹkan tí ìmọ́lẹ̀ bá tàn sí níí máa hàn kedere. Ohun gbogbo tí ó bá hàn kedere di ìmọ́lẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ orin kan ti sọ, pé, “Dìde, ìwọ tí ò ń sùn; jí dìde kúrò ninu òkú, Kristi yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ọ lára.”

Efe 5:3-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́. Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà, (tí í ṣé abọ̀rìṣà) tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn. Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀: (Nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí. Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé, “Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun, sí jíǹde kúrò nínú òkú Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”