Deuteronomi 17:18-19

Deuteronomi 17:18-19 YCB

Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn.