Deu 17:18-19
Deu 17:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Yio si ṣe, nigbati o ba joko lori itẹ́ ijọba rẹ̀, ki on ki o si kọ iwé ofin yi sinu iwé kan fun ara rẹ̀, lati inu eyiti mbẹ niwaju awọn alufa awọn ọmọ Lefi: Yio si wà lọdọ rẹ̀, on o si ma kà ninu rẹ̀ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo: ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ̀, lati ma pa gbogbo ọ̀rọ ofin yi mọ́ ati ilana wọnyi, lati ma ṣe wọn

Deu 17:18-19 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó gba ìwé òfin yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa ọmọ Lefi, kí ó dà á kọ sinu ìwé kan fún ara rẹ̀. Kí ẹ̀dà àwọn òfin yìí máa wà pẹlu rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; kí ó lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀, nípa pípa gbogbo òfin ati ìlànà wọnyi mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn
Deu 17:18-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn.