Daniẹli 5:22-31

Daniẹli 5:22-31 YCB

“Ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ rẹ̀, Belṣassari, ìwọ kò rẹ ara à rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ nǹkan wọ̀nyí. Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú ohun èlò inú tẹmpili rẹ̀ wá sí iwájú rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́rọ̀ tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. Nítorí náà, ó rán ọwọ́ tí ó kọ àkọlé yìí. “Èyí ni àkọlé náà tí a kọ: mene, mene, tekeli, peresini “Èyí ni nǹkan tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí: “ Mene: Ọlọ́run ti ṣírò ọjọ́ ìjọba rẹ. Ó sì ti mú u wá sí òpin. “ Tekeli: A ti gbé ọ lórí òṣùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n. “Peresini: A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Media àti àwọn Persia.” Nígbà náà ni Belṣassari pàṣẹ pé kí a wọ Daniẹli ní aṣọ elése àlùkò, kí a sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, a sì kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí kẹta ní ìjọba rẹ̀. Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni a pa Belṣassari, ọba àwọn ara Kaldea. Dariusi ará Media sì gba ìjọba nígbà tí ó di ọmọ ọdún méjìlélọ́gọ́ta.