DANIẸLI 5:22-31

DANIẸLI 5:22-31 YCE

“Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ ọmọ rẹ̀ Beṣasari, o kọ̀, o kò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ò ń gbéraga sí Ọlọrun ọ̀run. O ranṣẹ lọ kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun wá siwaju rẹ. Ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ayaba ati àwọn obinrin rẹ, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí waini. Ẹ sì ń yin àwọn oriṣa fadaka, ti wúrà, ti idẹ, ti irin, ti igi ati ti òkúta. Wọn kò ríran wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. O kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ. Ìdí nìyí tí ó fi rán ọwọ́ kan jáde láti kọ àkọsílẹ̀ yìí. “Ohun tí a kọ náà nìyí: ‘MENE, MENE, TEKELI, PERESINI.’ Ìtumọ̀ rẹ̀ sì nìyí: MENE, Ọlọrun ti ṣírò àwọn ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀. TEKELI, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò sì kún ojú ìwọ̀n. PERESINI, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mede ati àwọn ará Pasia.” Beṣasari bá pàṣẹ, pé kí wọ́n gbé ẹ̀wù elése àlùkò, ti àwọn olóyè, wọ Daniẹli, kí wọ́n sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Wọ́n kéde ká gbogbo ìjọba pé Daniẹli ni igbá kẹta ní ìjọba. Ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an ni wọ́n pa Beṣasari, ọba àwọn ará Kalidea. Dariusi, ará Mede, ẹni ọdún mejilelọgọta sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.