“Èyí ni àlá náà, nígbà yìí ni a ó wá sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. Ìwọ ọba jẹ́ ọba àwọn ọba. Ọlọ́run ọ̀run ti fi ìjọba agbára, títóbi àti ògo fún ọ; ní ọwọ́ rẹ ló fi gbogbo ènìyàn, àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run sí. Ní ibi gbogbo tí wọ́n ń gbé, ó ti fi ọ́ ṣe olórí i wọn. Ìwọ ni orí wúrà náà.
“Lẹ́yìn èyí ni ìjọba mìíràn yóò dìde, tí kò ní lágbára tó tìrẹ, lẹ́yìn in rẹ̀, ìjọba kẹta tí yóò dàbí idẹ, èyí tí yóò jẹ ọba lórí i gbogbo ayé. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìjọba kẹrin yóò wà, ìjọba náà yóò lágbára bí irin, gẹ́gẹ́ bí irin ti í fọ́, tó sì ń lọ gbogbo nǹkan àti bí irin ti í fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́, bẹ́ẹ̀ ni yóò fọ́ tí yóò sì lọ gbogbo àwọn tókù. Bí o ṣe rí i tí àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ àti apá kan irin, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yóò ṣe pín; ṣùgbọ́n yóò sì ní agbára irin díẹ̀ nínú rẹ̀, bí ó ṣe rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀. Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóò lágbára lápákan tí kò sì ní lágbára lápákan. Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀, báyìí ni àwọn ènìyàn yóò ṣe dàpọ̀ mọ́ ara wọn ní ti ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọn kò ní wà ní ìṣọ̀kan, bí irin kò ṣe dàpọ̀ mọ́ amọ̀.
“Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.” Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́.
“Ọlọ́run tí ó tóbi ti fihan ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.”
Nígbà náà, ni Nebukadnessari ọba dojúbolẹ̀ níwájú u Daniẹli ó sì fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọn kí ó mu ọrẹ àti òórùn tùràrí fún Daniẹli Ọba wí fún Daniẹli pé, “Dájúdájú Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba gbogbo àti olùfihàn àwọn àṣírí, nítorí tí ìwọ lè fi àṣírí yìí hàn.”
Nígbà náà ni ọba gbé Daniẹli ga, ó sì fún un ní ẹ̀bùn ńlá tí ó pọ̀. Ó sì fi ṣe olórí i gbogbo agbègbè ìjọba Babeli àti olórí gbogbo àwọn amòye Babeli. Daniẹli béèrè lọ́wọ́ ọba, ó sì yan Ṣadraki, Meṣaki, àti Abednego gẹ́gẹ́ bí alábojútó ìgbèríko Babeli ṣùgbọ́n Daniẹli fúnrarẹ̀ wà ní ààfin ọba.