Dan 2:36-49

Dan 2:36-49 Bibeli Mimọ (YBCV)

Eyiyi li alá na; awa o si sọ itumọ rẹ̀ pẹlu niwaju ọba. Iwọ ọba, li ọba awọn ọba: nitori Ọlọrun ọrun ti fi ijọba, agbara, ati ipá, ati ogo fun ọ. Ati nibikibi ti ọmọ enia wà, ẹranko igbẹ ati ẹiyẹ oju-ọrun li o si fi le ọ lọwọ, o si ti fi ọ ṣe alakoso lori gbogbo wọn. Iwọ li ori wura yi. Lẹhin rẹ ni ijọba miran yio si dide ti yio rẹ̀hin jù ọ, ati ijọba kẹta miran ti iṣe ti idẹ, ti yio si ṣe alakoso lori gbogbo aiye. Ijọba kẹrin yio si le bi irin; gẹgẹ bi irin ti ifọ tũtu, ti si iṣẹgun ohun gbogbo: ati gẹgẹ bi irin na ti o fọ gbogbo wọnyi, bẹ̃ni yio si fọ tũtu ti yio si lọ̀ wọn kunna. Ati gẹgẹ bi iwọ ti ri ẹsẹ ati ọmọkasẹ ti o jẹ apakan amọ̀ amọkoko, ati apakan irin, ni ijọba na yio yà si ara rẹ̀; ṣugbọn ipá ti irin yio wà ninu rẹ̀, niwọn bi iwọ ti ri irin ti o dapọ mọ amọ̀. Gẹgẹ bi ọmọkasẹ na ti jẹ apakan irin ati apakan amọ̀, bẹ̃li apakan ijọba na yio lagbara, apakan yio si jẹ ohun fifọ. Ati gẹgẹ bi iwọ si ti ri irin ti o dapọ mọ amọ̀, nwọn o da ara wọn pọ mọ iru-ọmọ enia, ṣugbọn nwọn kì yio fi ara wọn mọ ara wọn, gẹgẹ bi irin kì ti idapọ mọ amọ̀. Li ọjọ awọn ọba wọnyi li Ọlọrun ọrun yio gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a kì yio le parun titi lai: a kì yio si fi ijọba na le orilẹ-ède miran lọwọ, yio si fọ tutu, yio si pa gbogbo ijọba wọnyi run, ṣugbọn on o duro titi lailai. Gẹgẹ bi iwọ si ti ri ti okuta na wá laisi ọwọ lati òke wá, ti o si fọ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wura wọnni tutu; Ọlọrun titobi ti fi hàn fun ọba, ohun ti mbọ wá ṣe lẹhin ọla: otitọ si li alá na, itumọ rẹ̀ si daju. Nigbana ni Nebukadnessari, ọba, wolẹ o si doju rẹ̀ bolẹ, o si fi ori balẹ fun Danieli, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o ṣe ẹbọ-ọrẹ ati õrùn didùn fun u. Ọba da Danieli lohùn, o si wipe, Lõtọ ni, pe Ọlọrun nyin li Ọlọrun awọn ọlọrun ati Oluwa awọn ọba, ati olufihàn gbogbo aṣiri, nitori ti iwọ le fi aṣiri yi hàn. Nigbana li ọba sọ Danieli di ẹni-nla, o si fun u li ẹ̀bun nla pupọ, o si fi i jẹ olori gbogbo igberiko Babeli, ati olori onitọju gbogbo awọn ọlọgbọ́n Babeli. Danieli si bère lọwọ ọba, o si fi Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego jẹ olori ọ̀ran igberiko Babeli; ṣugbọn Danieli joko li ẹnu-ọ̀na ãfin ọba.

Dan 2:36-49 Yoruba Bible (YCE)

“Àlá náà nìyí; nisinsinyii, n óo sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. Kabiyesi, ìwọ ọba àwọn ọba ni Ọlọrun ọ̀run fún ní ìjọba, agbára, ipá ati ògo. Ọlọrun fi gbogbo eniyan jìn ọ́, níbi yòówù tí wọn ń gbé, ati gbogbo ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, pé kí o máa jọba lórí wọn, ìwọ ni orí wúrà náà. Lẹ́yìn rẹ ni ìjọba mìíràn yóo dìde tí kò ní lágbára tó tìrẹ. Lẹ́yìn èyí ni ìjọba kẹta, tí ó jẹ́ ti idẹ, yóo jọba lórí gbogbo ayé. Nígbà tí ó bá yá, ìjọba kẹrin yóo dé, tí yóo le koko bíi irin (nítorí pé irin a máa fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́ ni); bíi irin ni ìjọba yìí yóo fọ́ àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ túútúú. Bí o sì ti rí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ ati ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóo pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ṣugbọn agbára irin yóo hàn lára rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀. Bí ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ sì ti jẹ́ àdàlú amọ̀ ati irin, bẹ́ẹ̀ ni apá kan ìjọba náà yóo lágbára, apá kan kò sì ní lágbára. Bí o ti rí amọ̀ tí ó dàpọ̀ mọ́ irin, bẹ́ẹ̀ ni àwọn apá kinni keji yóo máa dàpọ̀ ní igbeyawo, ṣugbọn wọn kò ní darapọ̀, gẹ́gẹ́ bí irin kò ti lè darapọ̀ mọ́ amọ̀. Ní àkókò àwọn ìjọba wọnyi ni Ọlọrun ọ̀run yóo gbé ìjọba kan dìde tí a kò ní lè parun, a kò sì ní fi ìjọba náà fún ẹlòmíràn. Yóo fọ́ àwọn ìjọba wọnyi túútúú, yóo pa wọ́n run, yóo sì dúró laelae. Bí o ti rí i pé ara òkè kan ni òkúta yìí ti là, láìjẹ́ pé eniyan kan ni ó là á, tí o sì rí i pé ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wúrà túútúú, Ọlọrun tí ó tóbi ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han ọba. Òtítọ́ ni àlá yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì dájú.” Ọba bá wólẹ̀ níwájú Daniẹli, ó fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n rúbọ kí wọ́n sì sun turari sí Daniẹli. Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.” Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni. Daniẹli gba àṣẹ lọ́wọ́ ọba, ó fi Ṣadiraki, Meṣaki, ati Abedinego ṣe alákòóso àwọn agbègbè Babiloni, ṣugbọn òun wà ní ààfin.

Dan 2:36-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Èyí ni àlá náà, nígbà yìí ni a ó wá sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. Ìwọ ọba jẹ́ ọba àwọn ọba. Ọlọ́run ọ̀run ti fi ìjọba agbára, títóbi àti ògo fún ọ; ní ọwọ́ rẹ ló fi gbogbo ènìyàn, àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run sí. Ní ibi gbogbo tí wọ́n ń gbé, ó ti fi ọ́ ṣe olórí i wọn. Ìwọ ni orí wúrà náà. “Lẹ́yìn èyí ni ìjọba mìíràn yóò dìde, tí kò ní lágbára tó tìrẹ, lẹ́yìn in rẹ̀, ìjọba kẹta tí yóò dàbí idẹ, èyí tí yóò jẹ ọba lórí i gbogbo ayé. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìjọba kẹrin yóò wà, ìjọba náà yóò lágbára bí irin, gẹ́gẹ́ bí irin ti í fọ́, tó sì ń lọ gbogbo nǹkan àti bí irin ti í fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́, bẹ́ẹ̀ ni yóò fọ́ tí yóò sì lọ gbogbo àwọn tókù. Bí o ṣe rí i tí àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ àti apá kan irin, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yóò ṣe pín; ṣùgbọ́n yóò sì ní agbára irin díẹ̀ nínú rẹ̀, bí ó ṣe rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀. Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóò lágbára lápákan tí kò sì ní lágbára lápákan. Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀, báyìí ni àwọn ènìyàn yóò ṣe dàpọ̀ mọ́ ara wọn ní ti ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọn kò ní wà ní ìṣọ̀kan, bí irin kò ṣe dàpọ̀ mọ́ amọ̀. “Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.” Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́. “Ọlọ́run tí ó tóbi ti fihan ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.” Nígbà náà, ni Nebukadnessari ọba dojúbolẹ̀ níwájú u Daniẹli ó sì fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọn kí ó mu ọrẹ àti òórùn tùràrí fún Daniẹli Ọba wí fún Daniẹli pé, “Dájúdájú Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba gbogbo àti olùfihàn àwọn àṣírí, nítorí tí ìwọ lè fi àṣírí yìí hàn.” Nígbà náà ni ọba gbé Daniẹli ga, ó sì fún un ní ẹ̀bùn ńlá tí ó pọ̀. Ó sì fi ṣe olórí i gbogbo agbègbè ìjọba Babeli àti olórí gbogbo àwọn amòye Babeli. Daniẹli béèrè lọ́wọ́ ọba, ó sì yan Ṣadraki, Meṣaki, àti Abednego gẹ́gẹ́ bí alábojútó ìgbèríko Babeli ṣùgbọ́n Daniẹli fúnrarẹ̀ wà ní ààfin ọba.