Daniẹli 1

1
Ẹ̀kọ́ Daniẹli ní Babeli
1Ní ọdún kẹta tí Jehoiakimu jẹ ọba Juda, Nebukadnessari ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kọlù ú pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 2Olúwa sì fa Jehoiakimu ọba Juda lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Babeli, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà rẹ̀.
3Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá. 4Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli. 5Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba.
6Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Juda: Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah. 7Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun: Ó fún Daniẹli ní Belteṣassari, ó fún Hananiah ní Ṣadraki, ó fún Miṣaeli ní Meṣaki àti Asariah ní Abednego.
8Ṣùgbọ́n Daniẹli pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun kò ní ba ara òun jẹ́ pẹ̀lú oúnjẹ àti wáìnì ọba, nígbà náà ni ó gba ààyè lọ́wọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà wí pé òun kò fẹ́ ba ara òun jẹ́ ní ọ̀nà yìí. 9Ọlọ́run mú kí Daniẹli rí ojúrere àti àánú gbà láti ọwọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà, 10Ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Daniẹli pé, “Mo bẹ̀rù olúwa mi, ẹni tí o ti pèsè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ. Báwo ni ìrísí rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ? Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba.”
11Nígbà náà ni Daniẹli sọ fún olùṣọ́ tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn lórí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah pé, 12Jọ̀wọ́ dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá: Má ṣe fún wa ní ohun kankan, àfi ewébẹ̀ láti jẹ àti omi láti mu. 13Nígbà náà ni kí o fi ìrísí i wa wé ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba, kí o sì ṣe àwa ìránṣẹ́ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú u bí o bá ṣe rí i sí. 14Bẹ́ẹ̀ ni ó sì gbà láti dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá.
15Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwàá ara wọn le, wọ́n sì sanra ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba lọ. 16Bẹ́ẹ̀ ni olùṣọ́ mú oúnjẹ àdídùn àti wáìnì tí ó yẹ kí wọ́n mu kúrò, ó sì fún wọn ní ewébẹ̀ dípò rẹ̀.
17Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òye nínú gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Daniẹli sì ní òye ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí.
18Ní òpin ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá síwájú ọba Nebukadnessari. 19Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah; Nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba. 20Nínú gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n àti òye tí ọba ń béèrè lọ́wọ́ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọ́n tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀.
21Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kìn-ín-ní ọba Kirusi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Daniẹli 1: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀