Ìṣe àwọn Aposteli 21:18-36

Ìṣe àwọn Aposteli 21:18-36 YCB

Ní ọjọ́ kejì, a bá Paulu lọ sọ́dọ̀ Jakọbu; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀. Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrín àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin. Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrín àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mose sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn. Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá péjọpọ̀: dájúdájú wọn yóò gbọ́ pé, ìwọ dé. Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe: Àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́; Àwọn ni kí ìwọ mú, kí o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkára rẹ ń rìn déédé, ìwọ sì ń pa òfin Mose mọ́. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti àgbèrè.” Nígbà náà ni Paulu mú àwọn ọkùnrin náà; ní ọjọ́ kejì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹmpili lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olúkúlùkù wọn. Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Asia wá rí i ni tẹmpili, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un. Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbà wá: Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn ènìyàn, àti sí òfin, àti sí ibí yìí: àti pẹ̀lú ó sì mú àwọn ará Giriki wá sínú tẹmpili, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.” Nítorí wọ́n tí rí Tirofimu ará Efesu pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Paulu mú wá sínú tẹmpili. Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdò, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Paulu, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹmpili: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn. Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu. Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe. Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun. Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”