Iṣe Apo 21:18-36
Iṣe Apo 21:18-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kejì, a bá Paulu lọ sọ́dọ̀ Jakọbu; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀. Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrín àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin. Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrín àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mose sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn. Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá péjọpọ̀: dájúdájú wọn yóò gbọ́ pé, ìwọ dé. Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe: Àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́; Àwọn ni kí ìwọ mú, kí o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkára rẹ ń rìn déédé, ìwọ sì ń pa òfin Mose mọ́. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti àgbèrè.” Nígbà náà ni Paulu mú àwọn ọkùnrin náà; ní ọjọ́ kejì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹmpili lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olúkúlùkù wọn. Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Asia wá rí i ni tẹmpili, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un. Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbà wá: Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn ènìyàn, àti sí òfin, àti sí ibí yìí: àti pẹ̀lú ó sì mú àwọn ará Giriki wá sínú tẹmpili, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.” Nítorí wọ́n tí rí Tirofimu ará Efesu pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Paulu mú wá sínú tẹmpili. Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdò, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Paulu, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹmpili: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn. Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu. Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe. Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun. Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”
Iṣe Apo 21:18-36 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ni ijọ keji awa ba Paulu lọ sọdọ Jakọbu; gbogbo awọn alàgba si wà nibẹ̀. Nigbati o si kí wọn tan, o ròhin ohun gbogbo lẹsẹsẹ ti Ọlọrun ṣe lãrin awọn Keferi nipa iṣẹ-iranṣẹ rẹ̀. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn yin Ọlọrun logo, nwọn si wi fun u pe, Arakunrin, iwọ ri iye ẹgbẹgbẹrun ninu awọn Ju ti o gbagbọ, gbogbo nwọn li o si ni itara fun ofin. Nwọn si ti ròhin rẹ fun wọn pe, Iwọ nkọ́ gbogbo awọn Ju ti o wà lãrin awọn Keferi pe, ki nwọn ki o kọ̀ Mose silẹ, o si nwi fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe kọ awọn ọmọ wọn ni ilà mọ́, ati ki nwọn ki o máṣe rìn gẹgẹ bi àṣa wọn. Njẹ ewo ni ṣiṣe? ijọ kò le ṣaima pejọ pọ̀: dajudaju nwọn ó gbọ́ pe, iwọ de. Njẹ eyi ti awa ó wi fun ọ yi ni ki o ṣe: Awa li ọkunrin mẹrin ti nwọn ni ẹ̀jẹ́ lara wọn; Awọn ni ki iwọ ki o mu, ki o si ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn ki o si ṣe inawo wọn, ki nwọn ki o le fá ori wọn: gbogbo enia yio si mọ̀ pe, kò si otitọ kan ninu ohun ti nwọn gbọ si ọ; ṣugbọn pe, iwọ tikararẹ nrìn dede pẹlu, iwọ si npa ofin mọ́. Ṣugbọn niti awọn Keferi ti o gbagbọ́, awa ti kọwe, a si ti pinnu rẹ̀ pe, ki nwọn pa ara wọn mọ kuro ninu ohun ti a fi rubọ si oriṣa, ati ẹ̀jẹ ati ohun ilọlọrùnpa, ati àgbere. Nigbana ni Paulu mu awọn ọkunrin na; ni ijọ keji o ṣe iwẹnumọ pẹlu wọn, o si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o sọ ìgba ti ọjọ ìwẹ̀numọ́ na yio pé titi a fi rubọ fun olukuluku wọn. Nigbati ọjọ meje si fẹrẹ pé, ti awọn Ju ti o ti Asia wa ri i ni tẹmpili, nwọn rú gbogbo awọn enia soke, nwọn nawọ́ mu u. Nwọn nkigbe wipe, Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbà wa: Eyi li ọkunrin na, ti nkọ́ gbogbo enia nibigbogbo lòdi si awọn enia, ati si ofin, ati si ibi yi: ati pẹlu o si mu awọn ara Hellene wá si tẹmpili, o si ti ba ibi mimọ́ yi jẹ. Nitori nwọn ti ri Trofimu ará Efesu pẹlu rẹ̀ ni ilu, ẹniti nwọn ṣebi Paulu mu wá sinu tẹmpili. Gbogbo ilu si rọ́, awọn enia si sure jọ: nwọn si mu Paulu, nwọn si wọ́ ọ jade kuro ninu tẹmpili: lojukanna a si tì ilẹkun. Bi nwọn si ti nwá ọ̀na ati pa a, ìhin de ọdọ olori ẹgbẹ ọmọ-ogun pe, gbogbo Jerusalemu dàrú. Lojukanna o si ti mu awọn ọmọ-ogun ati awọn balogun ọrún, o si sure sọkalẹ tọ̀ wọn lọ: nigbati nwọn si ri olori ogun ati awọn ọmọ-ogun, nwọn dẹkun lilu Paulu. Nigbana li olori ogun sunmọ wọn, o si mu u, o paṣẹ pe ki a fi ẹ̀wọn meji dè e; o si bère ẹniti iṣe, ati ohun ti o ṣe. Awọn kan nkígbe ohun kan, awọn miran nkigbe ohun miran ninu awujọ: nigbati kò si le mọ̀ eredi irukerudò na dajudaju, o paṣẹ ki nwọn ki o mu u lọ sinu ile-olodi. Nigbati o si de ori atẹgùn, gbigbé li a gbé e soke lọwọ awọn ọmọ-ogun nitori iwa-ipa awọn enia. Nitori ọ̀pọ enia gbátì i, nwọn nkigbe pe, Mu u kuro.
Iṣe Apo 21:18-36 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ keji, Paulu bá lọ sọ́dọ̀ Jakọbu. Gbogbo àwọn àgbààgbà ni wọ́n pésẹ̀ sibẹ. Nígbà tí Paulu kí wọn tán, ó ròyìn lẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ tí Ọlọrun lo òun láti ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun. Àwọn náà wá sọ fún un pé, “Wò ó ná, arakunrin, ṣé o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn Juu tí ó gba Jesu gbọ́, tí gbogbo wọn sì ní ìtara sí Òfin Mose. Wọ́n ń sọ nípa rẹ pé ò ń kọ́ gbogbo àwọn Juu tí ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn pé kí wọ́n yapa kúrò ninu ìlànà Mose. Wọ́n ní o sọ pé kí wọn má kọ ọmọ wọn nílà; àtipé kí wọn má tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn mọ́. Èwo ni ṣíṣe? Ó dájú pé wọn á gbọ́ pé o ti dé. Bí a bá ti wí fún ọ ni kí o ṣe. Àwọn ọkunrin mẹrin kan wà lọ́dọ̀ wa tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́. Mú wọn, kí o lọ bá wọn wẹ ẹ̀jẹ́ náà kúrò. San gbogbo owó tí wọn óo bá ná ati tìrẹ náà. Kí wọn wá fá orí wọn. Èyí yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé kò sí òótọ́ ninu gbogbo nǹkan tí wọn ń sọ nípa rẹ. Wọn yóo mọ̀ pé Juu hánún-hánún ni ọ́ àtipé ò ń pa Òfin Mose mọ́. Ní ti àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n gba Jesu gbọ́, a ti kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún oúnjẹ tí a ti fi rúbọ sí oriṣa, ati ẹ̀jẹ̀, ati ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí wọn sì ṣọ́ra fún àgbèrè.” Ní ọjọ́ keji, Paulu mú àwọn ọkunrin náà, ó ṣe ètò láti wẹ ẹ̀jẹ́ wọn kúrò, ati tirẹ̀ pẹlu. Ó wọ Tẹmpili lọ láti lọ ṣe ìfilọ̀ ọjọ́ tí àkókò ìwẹ̀nùmọ́ wọn yóo parí, tí òun yóo mú ọrẹ ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn wá. Nígbà tí ọjọ́ meje náà fẹ́rẹ̀ pé, àwọn Juu láti Esia rí Paulu ninu Tẹmpili. Wọ́n bá ké ìbòòsí láàrin gbogbo èrò, wọ́n sì dọwọ́ bo Paulu, wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ gbani o! Ọkunrin tí ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo láti lòdì sí orílẹ̀-èdè wa ati Òfin Mose ati ilé yìí nìyí. Ó tún mú àwọn Giriki wọ inú Tẹmpili; ó wá sọ ibi mímọ́ yìí di àìmọ́.” Wọ́n sọ báyìí nítorí pé wọ́n ti kọ́kọ́ rí Tirofimọsi ará Efesu pẹlu Paulu láàrin ìlú, wọ́n wá ṣebí Paulu mú un wọ inú Tẹmpili ni. Gbogbo ìlú bá dàrú. Àwọn eniyan ń rọ́ lọ sọ́dọ̀ Paulu. Wọ́n bá mú un, wọ́n wọ́ ọ jáde kúrò ninu Tẹmpili. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n bá ti gbogbo ìlẹ̀kùn. Wọ́n fẹ́ pa á ni ìròyìn bá kan ọ̀gá àwọn ọmọ-ogun pé gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. Lójú kan náà ó bá mú àwọn ọmọ-ogun pẹlu àwọn balogun ọ̀rún tí ó wà lábẹ́ rẹ̀, ó sáré lọ bá wọn. Nígbà tí àwọn èrò rí ọ̀gágun ati àwọn ọmọ-ogun, wọ́n dáwọ́ dúró, wọn kò lu Paulu mọ́. Ọ̀gágun bá súnmọ́ Paulu, ó mú un, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é. Ó wá wádìí ẹni tí ó jẹ́ ati ohun tí ó ṣe. Àwọn kan ninu èrò ń sọ nǹkankan; àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. Nígbà tí ọ̀gágun náà kò lè mọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà nítorí ariwo èrò, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun. Nígbà tí wọ́n dé àtẹ̀gùn ilé, gbígbé ni àwọn ọmọ-ogun níláti gbé Paulu wọlé nítorí ojú àwọn èrò ti ranko. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé wọn, tí wọn ń kígbe pé, “Ẹ pa á!”