Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin. Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé:
Àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà,
Tí ó jẹ́ ti aláìkọlà tí ó wà ní Antioku, àti ní Siria: àti ní Kilikia.
Níwọ́n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín ní ọkàn padà, (wí pé, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣàìmá pa òfin Mose mọ́) ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ: Ó yẹ lójú àwa, bí wa ti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Barnaba àti Paulu àwọn olùfẹ́ wa. Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi. Nítorí náà àwa rán Judasi àti Sila àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín. Nítorí ó dára lójú Ẹ̀mí Mímọ́, àti lójú wa, kí a má ṣe di ẹrù le é yin lórí, bí kò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì; í ẹ̀yin fàsẹ́yìn kúrò nínú ẹran ti à pa bọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti nínú àgbèrè. Bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere.
Àlàáfíà.
Ǹjẹ́ nígbà tí wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá si Antioku. Nígbà tí wọn sì pé àwọn ìjọ papọ̀, wọn fi ìwé náà fún wọn. Nígbà tí wọn sì kà á, wọ́n yọ̀ fún ìtùnú náà. Bí Judasi àti Sila tìkára wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le. Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá. (Ṣùgbọ́n ó wu Sila láti gbé ibẹ̀.) Paulu àti Barnaba sì dúró díẹ̀ ni Antioku, wọ́n ń kọ́ni, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn.