Nigbana li o tọ́ loju awọn aposteli, ati awọn àgbagbà pẹlu gbogbo ijọ, lati yàn enia ninu wọn, ati lati ran wọn lọ si Antioku pẹlu Paulu on Barnaba: Juda ti a npè apele rẹ̀ ni Barsaba, ati Sila, ẹniti o l'orukọ ninu awọn arakunrin.
Nwọn si kọ iwe le wọn lọwọ bayi pe, Awọn aposteli, ati awọn àgbagbà, ati awọn arakunrin, kí awọn arakunrin ti o wà ni Antioku, ati ni Siria, ati ni Kilikia ninu awọn Keferi:
Niwọnbi awa ti gbọ́ pe, awọn kan ti o ti ọdọ wa jade lọ fi ọ̀rọ yọ nyin li ẹnu, ti nwọn nyi nyin li ọkàn po, wipe, Ẹnyin kò gbọdọ ṣaima kọ ilà, ati ṣaima pa ofin Mose mọ́: ẹniti awa kò fun li aṣẹ:
O yẹ loju awa, bi awa ti fi imọ ṣọkan lati yàn enia ati lati rán wọn si nyin, pẹlu Barnaba on Paulu awọn olufẹ wa.
Awọn ọkunrin ti o fi ẹmí wọn wewu nitori orukọ Oluwa wa Jesu Kristi.
Nitorina awa rán Juda on Sila, awọn ti yio si fi ọ̀rọ ẹnu sọ ohun kanna fun nyin.
Nitori o dara loju Ẹmi Mimọ́, ati loju wa, ki a máṣe dì ẹrù kà nyin, jù nkan ti a ko le ṣe alaiṣe wọnyi lọ:
Ki ẹnyin ki o fà sẹhin kuro ninu ẹran apabọ oriṣa, ati ninu ẹ̀jẹ ati ninu ohun ilọlọrun-pa, ati ninu àgbere: ninu ohun ti, bi ẹnyin ba pa ara nyin mọ́ kuro, ẹnyin ó ṣe rere. Alafia.
Njẹ nigbati nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ, nwọn sọkalẹ wá si Antioku: nigbati nwọn si pè apejọ, nwọn fi iwe na fun wọn.
Nigbati nwọn si kà a, nwọn yọ̀ fun itunu na.
Bi Juda on Sila tikarawọn ti jẹ woli pẹlu, nwọn fi ọ̀rọ pipọ gbà awọn arakunrin niyanju, nwọn si mu wọn li ọkàn le.
Nigbati nwọn si pẹ diẹ, awọn arakunrin jọwọ wọn lọwọ lọ li alafia si ọdọ awọn ti o ran wọn.
Ṣugbọn o wù Sila lati gbé ibẹ̀.
Paulu on Barnaba si duro diẹ ni Antioku, nwọn nkọ́ni, nwọn si nwasu ọ̀rọ Oluwa, ati awọn pipọ miran pẹlu wọn.