Àwọn ọkùnrin kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arákùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mose, ẹ̀yin kí yóò lè là.” Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí. Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà: wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin. Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.
Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú ẹ̀yà àwọn Farisi tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mose mọ́.”
Àwọn aposteli àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí. Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Peteru dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìhìnrere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́. Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olùmọ̀-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa. Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárín àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́. Ǹjẹ́ nítorí náà èéṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù? Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jesu àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.”
Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi etí sí Barnaba àti Paulu, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrín àwọn aláìkọlà. Lẹ́yìn tí wọn sì dákẹ́, Jakọbu dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi: Simeoni ti ròyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojú wo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀. Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe déédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
“ ‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà,
èmi ó sì tún àgọ́ Dafidi pa tí ó ti wó lulẹ̀:
èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́,
èmi ó sì gbé e ró.
Kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa,
àti gbogbo àwọn kèfèrí, lára ẹni tí a ń pe orúkọ mi,’
ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí,
ẹni tí ó sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá.
“Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu. Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fà sẹ́hìn kúrò nínú oúnjẹ tí a ṣe fún òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀. Nítorí òfin Mose nígbà àtijọ́ ṣá ní a ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú Sinagọgu ni ọjọọjọ́ ìsinmi.”