Àwọn kan wá láti Judia tí wọn ń kọ́ àwọn onigbagbọ pé, “Bí ẹ kò bá kọlà gẹ́gẹ́ bí àṣà ati Òfin Mose, a kò lè gbà yín là!” Ó di ọ̀rọ̀ líle ati àríyànjiyàn ńlá láàrin àwọn ati Paulu ati Banaba. Ni ìjọ bá pinnu pé kí Paulu ati Banaba ati àwọn mìíràn láàrin wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli ati àwọn alàgbà ní Jerusalẹmu láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.
Àwọn ìjọ sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n wá gba Fonike ati Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ń yipada di onigbagbọ. Èyí mú kí inú gbogbo àwọn onigbagbọ tí wọ́n gbọ́ dùn pupọ. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, gbogbo ìjọ, ati àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀. Wọ́n wá ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun ti ṣe fún wọ́n. Àwọn kan láti inú ẹgbẹ́ àwọn Farisi tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ wá dìde. Wọ́n ní, “Dandan ni pé kí á kọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí ó bá fẹ́ di onigbagbọ nílà, kí á sì pàṣẹ fún wọn láti máa pa Òfin Mose mọ́.”
Gbogbo àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà bá péjọ láti rí sí ọ̀rọ̀ yìí. Àríyànjiyàn pupọ ni ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Peteru bá dìde, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ̀yin gan-an mọ̀ pé ní àtijọ́ Ọlọrun yàn mí láàrin yín pé láti ẹnu mi ni àwọn tí kì í ṣe Juu yóo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere, kí wọ́n lè gba Jesu gbọ́. Ọlọrun olùmọ̀ràn ọkàn fún wọn ní ìwé ẹ̀rí nígbà tí ó fún wọn ní Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti fún wa. Kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàrin àwa ati àwọn; ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nítorí wọ́n gba Jesu gbọ́. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ní ṣe tí ẹ fi fẹ́ dán Ọlọrun wò, tí ẹ fẹ́ gbé àjàgà tí àwọn baba wa ati àwa náà kò tó rù, rù àwọn ọmọ-ẹ̀yìn? A gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Jesu Oluwa ni a fi gbà wá là, gẹ́gẹ́ bí a ti fi gba àwọn náà là.”
Ńṣe ni gbogbo àwùjọ dákẹ́ jẹ́ẹ́. Wọ́n wá fetí sílẹ̀ sí ohun tí Banaba ati Paulu níí sọ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí wọ́n níí sọ, Jakọbu bá fèsì pé, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ fetí sí mi. Simoni ti ròyìn ọ̀nà tí Ọlọrun kọ́kọ́ fi ṣe ìkẹ́ àwọn tí kì í ṣe Juu kí ó lè mú ninu wọn fi ṣe eniyan tirẹ̀. Ọ̀rọ̀ àwọn wolii bá èyí mu, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,
‘Lẹ́yìn èyí, n óo tún ilé Dafidi tí ó ti wó kọ́.
N óo tún ahoro rẹ̀ mọ,
n óo sì gbé e ró.
Báyìí ni gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo máa wá Oluwa,
ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo ti pè láti jẹ́ tèmi.
Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí,
ó sì jẹ́ kí á mọ ọ̀rọ̀ náà láti ìgbà àtijọ́-tijọ́.’
“Ní tèmi, èrò mi ni pé kí á má tún yọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n yipada sí Ọlọrun lẹ́nu mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀ kí á kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n takété sí ohunkohun tí ó bá ti di àìmọ́ nítorí pé a ti fi rúbọ sí oriṣa; kí wọn má ṣe àgbèrè, kí wọn má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa, kí wọn má sì jẹ ẹ̀jẹ̀. Nítorí láti ìgbà àtijọ́ ni wọ́n ti ń ké òkìkí Mose láti ìlú dé ìlú tí wọn sì ń ka ìwé rẹ̀ ninu gbogbo ilé ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”