Ṣeba kọjá nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli sí Abeli-Beti-Maaka, àti gbogbo àwọn ará Beri; wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú. Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì Ṣeba ní Abeli-Beti-Maaka, wọ́n sì mọ odi ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Joabu sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀. Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹ sọ fún Joabu pé: Súnmọ́ ìhín yìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.” Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, “Ìwọ ni Joabu bí?”
Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi náà ni.”
Obìnrin náà sì wí fún un pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.”
Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi ń gbọ́.”
Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, “Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, ‘Gba ìdáhùn rẹ ní Abeli’ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà. Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti olóòtítọ́ ní Israẹli: ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli: èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní OLúWA mì.”
Joabu sì dáhùn wí pé, “Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun. Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Efraimu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikri, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọba, àní sí Dafidi: fi òun nìkan ṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.”
Obìnrin náà sì wí fún Joabu pé, “Wò ó, orí rẹ̀ ni a ó sì sọ láti inú odi wá.”
Obìnrin náà sì mú ìmọ́ràn rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣeba ọmọ Bikri lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Joabu. Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká ní ìlú náà, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀. Joabu sí padà lọ sí Jerusalẹmu àti sọ́dọ̀ ọba.
Joabu sì ni olórí gbogbo ogun Israẹli;
Benaiah ọmọ Jehoiada sì jẹ́ olórí àwọn Kereti, àti ti àwọn Peleti.
Adoniramu sì jẹ́ olórí àwọn agbowó òde;
Jehoṣafati ọmọ Ahiludi sì jẹ́ olùkọsílẹ̀ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú.
Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé;
Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà.
Ira pẹ̀lú, ará Jairi ni ń ṣe àlùfáà lọ́dọ̀ Dafidi.