II. Sam 20:14-26

II. Sam 20:14-26 YBCV

On kọja ninu gbogbo ẹya Israeli si Abeli ati si Betmaaka, ati gbogbo awọn ara Beriti; nwọn si kó ara wọn jọ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin pẹlu. Nwọn wá, nwọn si do tì i ni Abeli ti Betmaaka, nwọn si mọdi tì ilu na, odi na si duro ti odi ilu na: gbogbo enia ti mbẹ lọdọ Joabu si ngbiyanju lati wó ogiri na lulẹ. Obinrin ọlọgbọ́n kan si kigbe soke lati ilu na wá, pe, Fetisilẹ, fetisilẹ, emi bẹ̀ nyin, sọ fun Joabu pe, Sunmọ ihinyi emi o si ba ọ sọ̀rọ. Nigbati on si sunmọ ọdọ rẹ̀, obinrin na si wipe, Iwọ ni Joabu bi? on si dahùn wipe, Emi na ni. Obinrin na si wi fun u pe, Gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹbinrin rẹ. On si dahun wipe, Emi ngbọ́. O si sọ̀rọ, wipe, Nwọn ti nwi ṣaju pe niti bibere, nwọn o bere ni Abeli: bẹ̃ni nwọn si pari ọ̀ran na. Emi li ọkan ninu awọn ẹni alafia ati olõtọ ni Israeli: iwọ nwá ọ̀na lati pa ilu kan run ti o jẹ iyá ni Israeli: ẽṣe ti iwọ o fi gbe ini Oluwa mì? Joabu si dahùn wipe, Ki a má ri i, ki a má ri i lọdọ mi pe emi gbé mì tabi emi sì parun. Ọràn na kò ri bẹ̃; ṣugbọn ọkunrin kan lati oke Efraimu, ti orukọ rẹ̀ njẹ Ṣeba, ọmọ Bikri, li o gbe ọwọ́ rẹ̀ soke si ọba, ani si Dafidi: fi on nikanṣoṣo le wa lọwọ, emi o si fi ilu silẹ. Obinrin na si wi fun Joabu pe, Wõ, ori rẹ̀ li a o si sọ si ọ lati inu odi wá. Obinrin na si mu ìmọran rẹ̀ tọ gbogbo awọn enia na. Nwọn si bẹ́ Ṣeba ọmọ Bikri li ori, nwọn si sọ ọ si Joabu. On si fún ipè, nwọn si tuka kuro ni ilu na, olukuluku si agọ rẹ̀. Joabu si pada lọ si Jerusalemu ati sọdọ ọba. Joabu si li olori gbogbo ogun Israeli: Benaiah ọmọ Jehoiada si jẹ olori awọn Kereti, ati olori awọn Peleti: Adoramu si jẹ olori awọn agbowodè: Jehoṣafati ọmọ Ahiludi si jẹ akọwe nkan ti o ṣe ni ilu: Ṣefa si jẹ akọwe: Sadoku ati Abiatari si li awọn alufa. Ira pẹlu, ara Jairi ni nṣe alufa lọdọ Dafidi.