1 Samuẹli 2:1-21

1 Samuẹli 2:1-21 YCB

Hana sì gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ sí OLúWA; Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí OLúWA. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀. “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi OLúWA; kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ; kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa. “Má ṣe halẹ̀; má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni OLúWA, láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà. “Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́, àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè. Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe, àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní. Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje. Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára. “OLúWA pa ó sì sọ di ààyè; ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde. OLúWA sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀; ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè. Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo: “Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti OLúWA ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́, àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn. “Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí. A ó fọ́ àwọn ọ̀tá OLúWA túútúú; láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn; OLúWA yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé. “Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀, yóò si gbé ìwo ẹni ààmì òróró rẹ̀ sókè.” Elkana sì lọ sí Rama sí ilé rẹ̀, Ọmọ náà sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún OLúWA níwájú Eli àlùfáà. Àwọn ọmọ Eli sì jẹ́ ọmọ Beliali; wọn kò mọ OLúWA. Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀. Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí àgé tàbí ọpọ́n, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Israẹli tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣilo. Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìránṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfáà; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe tútù.” Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́,” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.” Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì tóbi gidigidi níwájú OLúWA: nítorí tí àwọn ènìyàn kórìíra ẹbọ OLúWA. Ṣùgbọ́n Samuẹli ń ṣe ìránṣẹ́ níwájú OLúWA, ọmọdé, ti a wọ̀ ní efodu ọ̀gbọ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mú wá fún un lọ́dọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún. Eli súre fún Elkana àti aya rẹ̀ pé, “Kí OLúWA fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún OLúWA.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn. OLúWA si bojú wo Hana, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Samuẹli ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú OLúWA.