Hana bá gbadura báyìí pé:
“Ọkàn mi kún fún ayọ̀ ninu OLUWA,
Ó sọ mí di alágbára;
mò ń fi àwọn ọ̀tá mi rẹ́rìn-ín,
nítorí mò ń yọ̀ pé OLUWA gbà mí là.
“Kò sí ẹni mímọ́ bíi OLUWA,
kò sí ẹlòmíràn,
àfi òun nìkan ṣoṣo.
Kò sí aláàbò kan tí ó dàbí Ọlọrun wa.
Má sọ̀rọ̀ pẹlu ìgbéraga mọ́,
má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìgbéraga ti ẹnu rẹ jáde,
nítorí Ọlọrun tí ó mọ ohun gbogbo ni OLUWA,
gbogbo ohun tí ẹ̀dá bá ṣe ni ó sì máa ń gbéyẹ̀wò.
Ọrun àwọn alágbára dá,
ṣugbọn àwọn aláìlágbára di alágbára.
Àwọn tí wọ́n rí oúnjẹ jẹ lájẹyó rí
ti di ẹni tí ń fi ara wọn ṣọfà nítorí oúnjẹ,
ṣugbọn àwọn tí ebi ti ń pa tẹ́lẹ̀ rí tí ń jẹ àjẹyó.
Àgàn ti di ọlọ́mọ meje,
ọlọ́mọ pupọ ti di aláìní.
OLUWA ni ó lè pa eniyan tán,
kí ó sì tún jí i dìde;
òun ni ó lè múni lọ sinu isà òkú,
tí ó sì tún lè fani yọ kúrò níbẹ̀.
OLUWA ni ó lè sọni di aláìní,
òun náà ni ó sì lè sọ eniyan di ọlọ́rọ̀.
Òun ni ó ń gbéni ga,
òun náà ni ó sì ń rẹ eniyan sílẹ̀.
OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀;
ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀,
láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba,
kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá.
Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé,
òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn.
“Yóo pa àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ mọ́,
ṣugbọn yóo mú kí àwọn eniyan burúkú parẹ́ ninu òkùnkùn;
nítorí pé, kì í ṣe nípa agbára eniyan, ni ẹnikẹ́ni lè fi ṣẹgun.
Àwọn ọ̀tá OLUWA yóo parun;
OLUWA yóo sán ààrá pa wọ́n láti ojú ọ̀run wá.
OLUWA yóo ṣe ìdájọ́ gbogbo ayé,
yóo fún ọba rẹ̀ lágbára,
yóo sì fún ẹni tí ó yàn ní ìṣẹ́gun.”
Lẹ́yìn náà, Elikana pada sí ilé rẹ̀ ní Rama. Ṣugbọn Samuẹli dúró sí Ṣilo, ó ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, lábẹ́ alufaa Eli.
Aláìníláárí ẹ̀dá ni àwọn ọmọ Eli mejeeji. Wọn kò bọ̀wọ̀ fún OLUWA rárá. Ó jẹ́ àṣà àwọn alufaa pé nígbà tí ẹnìkan bá wá rúbọ, iranṣẹ alufaa yóo wá, ti òun ti ọ̀pá irin oníga mẹta tí wọ́n fi ń yọ ẹran lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ń se ẹran náà lọ́wọ́ lórí iná, yóo ti ọ̀pá irin náà bọ inú ìkòkò ẹran, gbogbo ẹran tí ó bá yọ jáde á jẹ́ ti alufaa. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá wá rúbọ ní Ṣilo. Ati pé, kí wọ́n tilẹ̀ tó rẹ́ ọ̀rá tí wọ́n máa ń sun kúrò lára ẹran, iranṣẹ alufaa á wá, a sì wí fún ẹni tí ń rú ẹbọ pé kí ó fún òun ninu ẹran tí alufaa yóo sun jẹ, nítorí pé alufaa kò ní gba ẹran bíbọ̀ lọ́wọ́ olúwarẹ̀, àfi ẹran tútù.
Bí ẹni tí ń rú ẹbọ náà bá dá a lóhùn pé “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ sun ọ̀rá ẹran náà, lẹ́yìn náà kí o wá mú ohun tí ó bá wù ọ́.” Iranṣẹ alufaa náà á wí pé, “Rárá! Nisinsinyii ni kí o fún mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo mú un tipátipá.”
Ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn ọmọ Eli ń dá yìí burú pupọ lójú OLUWA, nítorí pé wọn kò náání ẹbọ OLUWA.
Ní gbogbo àkókò yìí, Samuẹli ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, ó sì jẹ́ ọmọde nígbà náà, a máa wọ ẹ̀wù efodu funfun. Ní ọdọọdún ni ìyá rẹ̀ máa ń dá ẹ̀wù kékeré, a sì mú un lọ́wọ́ lọ fún un, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ lọ, láti lọ rúbọ. Eli a máa súre fún Elikana ati Hana aya rẹ̀ pé, “OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí ọmọ mìíràn fún ọ, dípò èyí tí ó yà sọ́tọ̀ fún OLUWA.”
Lẹ́yìn náà, wọn yóo pada lọ sí ilé wọn.
OLUWA bukun Hana: ọmọkunrin mẹta, ati ọmọbinrin meji ni ó tún bí lẹ́yìn Samuẹli. Samuẹli sì ń dàgbà níbi tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA.