1 Samuẹli 2:1-2

1 Samuẹli 2:1-2 YCB

Hana sì gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ sí OLúWA; Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí OLúWA. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀. “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi OLúWA; kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ; kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.