I. Sam 2:1-2
I. Sam 2:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
HANNA si gbadura pe, Ọkàn mi yọ̀ si Oluwa, iwo mi li a si gbe soke si Oluwa: ẹnu mi si gboro lori awọn ọta mi; nitoriti emi yọ̀ ni igbala rẹ. Kò si ẹniti o mọ́ bi Oluwa: kò si ẹlomiran boyẹ̀ ni iwọ; bẹ̃ni kò si apata bi Ọlọrun wa.
Pín
Kà I. Sam 2I. Sam 2:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Hana bá gbadura báyìí pé: “Ọkàn mi kún fún ayọ̀ ninu OLUWA, Ó sọ mí di alágbára; mò ń fi àwọn ọ̀tá mi rẹ́rìn-ín, nítorí mò ń yọ̀ pé OLUWA gbà mí là. “Kò sí ẹni mímọ́ bíi OLUWA, kò sí ẹlòmíràn, àfi òun nìkan ṣoṣo. Kò sí aláàbò kan tí ó dàbí Ọlọrun wa.
Pín
Kà I. Sam 2I. Sam 2:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Hana sì gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ sí OLúWA; Ìwo agbára mi ni a sì gbé sókè sí OLúWA. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀tá mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni ìgbàlà rẹ̀. “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi OLúWA; kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ; kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.
Pín
Kà I. Sam 2