1 Samuẹli 18:1-16

1 Samuẹli 18:1-16 YCB

Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá Saulu sọ, ọkàn Jonatani di ọ̀kan pẹ̀lú ti Dafidi, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. Láti ọjọ́ náà Saulu pa Dafidi mọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì jẹ́ kí ó padà sí ilé baba rẹ̀ mọ́. Jonatani bá Dafidi dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. Jonatani sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dafidi pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀. Ohunkóhun tí Saulu bá rán an láti ṣe, Dafidi máa ṣe ní àṣeyọrí, Saulu náà sì fun un ní ipò tí ó ga jù láàrín àwọn ológun. Eléyìí sì tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, àti pẹ̀lú ó sì tẹ́ àwọn ìjòyè Saulu lọ́rùn pẹ̀lú. Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti pa Filistini, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Israẹli wá láti pàdé ọba Saulu pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tambori àti ohun èlò orin olókùn. Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé: “Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀ Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbàárún ní tirẹ̀.” Saulu sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, “Wọ́n ti gbé ògo fún Dafidi pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárún” ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan. Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba?” Láti ìgbà náà lọ ni Saulu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ojú ìlara wo Dafidi. Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Saulu, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dafidi sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Saulu sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dafidi pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dafidi yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì. Saulu sì ń bẹ̀rù Dafidi nítorí pé OLúWA wà pẹ̀lú Dafidi, ṣùgbọ́n ó ti fi Saulu sílẹ̀. Ó sì lé Dafidi jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan, Dafidi ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun. Dafidi sì ṣe ọlọ́gbọ́n ní gbogbo ìṣe rẹ̀, nítorí tí OLúWA wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí Saulu rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli àti Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó darí wọn lọ ní ìgbòkègbodò ogun wọn.