Lẹ́yìn tí Dafidi ati Saulu parí ọ̀rọ̀ wọn, ọkàn Jonatani, ọmọ Saulu fà mọ́ Dafidi lọpọlọpọ ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀. Saulu gba Dafidi sọ́dọ̀ ní ọjọ́ náà, kò sì jẹ́ kí ó pada sílé baba rẹ̀. Jonatani bá bá Dafidi dá majẹmu, nítorí pé ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ó bọ́ aṣọ tí ó wọ̀ fún Dafidi, ó sì kó ihamọra rẹ̀ pẹlu idà ati ọfà ati àmùrè rẹ̀ fún un. Dafidi ń ṣe àṣeyọrí ninu àwọn iṣẹ́ tí Saulu ń rán an. Nítorí náà, Saulu fi ṣe ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun rẹ̀. Èyí sì tẹ́ àwọn olórí yòókù lọ́rùn.
Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin. Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé,
“Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀,
ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.”
Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.” Láti ọjọ́ náà ni Saulu ti ń ṣe ìlara Dafidi.
Ní ọjọ́ keji, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bà lé Saulu, ó sì ń sọ kántankàntan láàrin ilé rẹ̀. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí ta hapu fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Saulu. Ó ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi ní àgúnmọ́ ògiri. Ó ju ọ̀kọ̀ náà nígbà meji, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́ lẹẹmejeeji.
Saulu bẹ̀rù Dafidi nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn OLUWA kọ òun sílẹ̀. Saulu mú un kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó fi ṣe olórí ẹgbẹrun ọmọ ogun, Dafidi sì ń darí àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó ń ṣe àṣeyọrí nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀. Saulu tún bẹ̀rù Dafidi sí i nítorí àwọn àṣeyọrí rẹ̀. Ṣugbọn gbogbo àwọn ará Israẹli ati Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó jẹ́ olórí tí ń ṣe àṣeyọrí.