Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀? Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́. Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì fi ọkàn ara wa balẹ̀ níwájú rẹ̀. Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi; nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.
Kà 1 Johanu 3
Feti si 1 Johanu 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 1 Johanu 3:16-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò