I. Joh 3:16-20

I. Joh 3:16-20 YBCV

Nipa eyi li awa mọ̀ ifẹ nitoriti o fi ẹmí rẹ̀ lelẹ fun wa: o si yẹ ki awa fi ẹmí wa lelẹ fun awọn ará. Ṣugbọn ẹniti o ba ni ohun ini aiye, ti o si ri arakunrin rẹ̀ ti iṣe alaini, ti o si sé ilẹkun ìyọ́nu rẹ̀ mọ ọ, bawo ni ifẹ Ọlọrun ti ngbé inu rẹ̀? Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki a fi ọrọ tabi ahọn fẹran, bikoṣe ni iṣe ati li otitọ. Ati nipa eyi li awa ó mọ̀ pe awa jẹ ti otitọ, ati pe awa o si dá ara wa loju niwaju rẹ̀, Ninu ohunkohun ti ọkàn wa ba ndá wa lẹbi; nitoripe Ọlọrun tobi jù ọkàn wa lọ, o si mọ̀ ohun gbogbo.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Joh 3:16-20