O. Sol 8:6-8

O. Sol 8:6-8 YBCV

Gbe mi ka aiya rẹ bi edidi, bi edidi le apá rẹ: nitori ifẹ lagbara bi ikú; ijowu si le bi isa-okú; jijo rẹ̀ dabi jijo iná, ani ọwọ iná Oluwa. Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata. Awa ni arabinrin kekere kan, on kò si ni ọmú: kili awa o ṣe fun arabinrin wa li ọjọ ti a o ba fẹ ẹ?