O. Sol 8:6-8
O. Sol 8:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná OLúWA. Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́; bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ. Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá. Àwa ní arábìnrin kékeré kan, òun kò sì ní ọmú, kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa, ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?
O. Sol 8:6-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbe mi ka aiya rẹ bi edidi, bi edidi le apá rẹ: nitori ifẹ lagbara bi ikú; ijowu si le bi isa-okú; jijo rẹ̀ dabi jijo iná, ani ọwọ iná Oluwa. Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata. Awa ni arabinrin kekere kan, on kò si ni ọmú: kili awa o ṣe fun arabinrin wa li ọjọ ti a o ba fẹ ẹ?
O. Sol 8:6-8 Yoruba Bible (YCE)
Gbé mi lé oókan àyà rẹ bí èdìdì ìfẹ́, bí èdìdì, ní apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú. Owú jíjẹ burú, àfi bí isà òkú. A máa jó bí iná, bí ọwọ́ iná tí ó lágbára. Ọ̀pọ̀ omi kò lè pa iná ìfẹ́, ìgbì omi kò sì lè tẹ̀ ẹ́ rì. Bí eniyan bá gbìyànjú láti fi gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ ra ìfẹ́, ẹ̀tẹ́ ni yóo fi gbà. A ní àbúrò obinrin kékeré kan, tí kò lọ́mú. Kí ni kí á ṣe fún arabinrin wa náà ní ọjọ́ tí wọ́n bá wá tọrọ rẹ̀?