ORIN SOLOMONI 8

8
1Ìbá wù mí kí o jẹ́ ọmọ ìyá mi ọkunrin,
kí ó jẹ́ pé ọmú kan náà ni a jọ mú dàgbà.
Bí mo bá pàdé rẹ níta,
tí mo fẹnu kò ọ́ lẹ́nu,
kì bá tí sí ẹni tí yóo fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.
2Ǹ bá sìn ọ́ wá sílé ìyá mi,
ninu ìyẹ̀wù ẹni tí ó tọ́ mi,
ǹ bá fún ọ ní waini dídùn mu,
àní omi èso Pomegiranate mi.
3Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní ìgbèrí mi,
kí o sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ fà mí mọ́ra!
4Mo kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin obinrin Jerusalẹmu,
pé ẹ kò gbọdọ̀ jí olùfẹ́ mi,
títí tí yóo fi wù ú láti jí.
Orin Kẹfa
Àwọn Obinrin
5Ta ní ń bọ̀ láti inú aṣálẹ̀ yìí,
tí ó fara ti olùfẹ́ rẹ̀?
Obinrin
Lábẹ́ igi èso ápù ni mo ti jí ọ,
níbi tí ìyá rẹ ti rọbí rẹ,
níbi tí ẹni tí ó bí ọ ti rọbí.
6Gbé mi lé oókan àyà rẹ bí èdìdì ìfẹ́,
bí èdìdì, ní apá rẹ;
nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú.
Owú jíjẹ burú, àfi bí isà òkú.
A máa jó bí iná,
bí ọwọ́ iná tí ó lágbára.
7Ọ̀pọ̀ omi kò lè pa iná ìfẹ́,
ìgbì omi kò sì lè tẹ̀ ẹ́ rì.
Bí eniyan bá gbìyànjú láti fi gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ ra ìfẹ́,
ẹ̀tẹ́ ni yóo fi gbà.
Àwọn Arakunrin Ọmọbinrin Náà
8A ní àbúrò obinrin kékeré kan,
tí kò lọ́mú.
Kí ni kí á ṣe fún arabinrin wa náà
ní ọjọ́ tí wọ́n bá wá tọrọ rẹ̀?
9Bí ó bá jẹ pé ògiri ni arabinrin wa,
à óo mọ ilé-ìṣọ́ fadaka lé e lórí.
Bí ó bá jẹ́ pé ìlẹ̀kùn ni,
pákó Kedari ni a óo fi yí i ká.
Obinrin
10Ògiri ni mí,
ọmú mi sì dàbí ilé-ìṣọ́;
ní ojú olùfẹ́ mi,
mo ní alaafia ati ìtẹ́lọ́rùn.
Ọkunrin
11Solomoni ní ọgbà àjàrà kan,
ní Baali Hamoni.
Ó fi ọgbà náà fún àwọn tí wọn yá a,
ó ní kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n owó fadaka wá,
fún èso ọgbà rẹ̀.
12Èmi ni mo ni ọgbà àjàrà tèmi,
ìwọ Solomoni lè ní ẹgbẹrun ìwọ̀n owó fadaka,
kí àwọn tí wọn yá ọgbà sì ní igba.
13Ìwọ tí ò ń gbé inú ọgbà,
àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ń dẹtí,
jẹ́ kí n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.
Obinrin
14Yára wá, olùfẹ́ mi,
yára bí egbin, tabi ọ̀dọ́ akọ àgbọ̀nrín,
sí orí àwọn òkè turari olóòórùn dídùn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN SOLOMONI 8: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀