MO si ri ọrun titun kan ati aiye titun kan: nitoripe ọrun ti iṣaju ati aiye iṣaju ti kọja lọ; okun kò si si mọ́.
Mo si ri ilu mimọ́ nì, Jerusalemu titun nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, ti a mura silẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọ́ fun ọkọ rẹ̀.
Mo si gbọ́ ohùn nla kan lati ori itẹ́ nì wá, nwipe, Kiyesi i, agọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mã ba wọn gbé, nwọn o si mã jẹ enia rẹ̀, ati Ọlọrun tikararẹ̀ yio wà pẹlu wọn, yio si mã jẹ Ọlọrun wọn.
Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn; kì yio si si ikú mọ́, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹ̃ni ki yio si irora mọ́: nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ.
Ẹniti o joko lori itẹ́ nì si wipe, Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtún. O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀: nitori ọ̀rọ wọnyi ododo ati otitọ ni nwọn.
O si wi fun mi pe, O pari. Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin. Emi ó si fi omi fun ẹniti ongbẹ ngbẹ lati orisun omi ìye lọfẹ̃.
Ẹniti o ba ṣẹgun ni yio jogún nkan wọnyi; emi o si mã jẹ Ọlọrun rẹ̀, on o si mã jẹ ọmọ mi.
Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè, ati oṣó, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ní ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji.
Ọkan ninu awọn angẹli meje nì, ti nwọn ni ìgo meje nì, ti o kún fun iyọnu meje ikẹhin si wá, o si ba mi sọ̀rọ wipe, Wá nihin, emi o fi iyawo, aya Ọdọ-Agutan, hàn ọ.
O si mu mi lọ ninu Ẹmí si òke nla kan ti o si ga, o si fi ilu nì hàn mi, Jerusalemu mimọ́, ti nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá,
Ti o ni ogo Ọlọrun: imọlẹ rẹ̀ si dabi okuta iyebiye gidigidi, ani bi okuta jasperi, o mọ́ bi kristali;
O si ni odi nla ati giga, o si ni ẹnubode mejila, ati ni awọn ẹnubode na angẹli mejila ati orukọ ti a kọ sara wọn ti iṣe orukọ awọn ẹ̀ya mejila ti awọn ọmọ Israeli:
Ni ìha ìla-õrùn ẹnubode mẹta; ni ìha ariwa ẹnubode mẹta; ni ìha gusù ẹnubode mẹta; ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹnubode mẹta.
Odi ilu na si ni ipilẹ mejila, ati lori wọn orukọ awọn Aposteli mejila ti Ọdọ-Agutan.
Ẹniti o si mba mi sọ̀rọ ni ifefe wura kan fun iwọn lati fi wọ̀n ilu na ati awọn ẹnubode rẹ̀, ati odi rẹ̀.
Ilu na si lelẹ ni ibú mẹrin li ọgbọgba, gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ si dọgba: o si fi ifefe nì wọ̀n ilu na, o jẹ ẹgbata oṣuwọn furlongi: gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ ati gìga rẹ̀ si dọ́gba.
O si wọ̀n odi rẹ̀, o jẹ ogoje igbọnwọ le mẹrin, gẹgẹ bi oṣuwọn enia, eyini ni, ti angẹli na.
Ohun ti a sì fi mọ odi na ni jasperi: ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí ti o mọ́ kedere.
A fi onirũru okuta iyebiye ṣe ipilẹ ogiri ilu na lọ́ṣọ. Ipilẹ ikini jẹ jasperi; ekeji, safiru; ẹkẹta, kalkedoni; ẹkẹrin, smaragdu:
Ẹkarun, sardoniki; ẹkẹfa, sardiu; ekeje, krisoliti; ẹkẹjọ berili; ẹkẹsan, topasi; ẹkẹwa, krisoprasu; ẹkọkanla, hiakinti; ekejila, ametisti.
Ẹnubode mejejila jẹ perli mejila: olukuluku ẹnubode jẹ perli kan; ọ̀na igboro ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí didán.
Emi kò si ri tẹmpili ninu rẹ̀: nitoripe Oluwa Ọlọrun Olodumare ni tẹmpili rẹ̀, ati Ọdọ-Agutan.
Ilu na kò si ni iwá õrùn, tabi oṣupa, lati mã tan imọlẹ si i: nitoripe ogo Ọlọrun li o ntàn imọlẹ si i, Ọdọ-Agutan si ni fitila rẹ̀.
Awọn orilẹ-ède yio si mã rìn nipa imọlẹ rẹ̀: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wá sinu rẹ̀.
A kì yio si sé awọn ẹnubode rẹ̀ rara li ọsán: nitori kì yio si oru nibẹ̀.
Nwọn o si ma mu ogo ati ọlá awọn orilẹ-ède wá sinu rẹ̀.
Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.