Ifi 21:1-27

Ifi 21:1-27 Bibeli Mimọ (YBCV)

MO si ri ọrun titun kan ati aiye titun kan: nitoripe ọrun ti iṣaju ati aiye iṣaju ti kọja lọ; okun kò si si mọ́. Mo si ri ilu mimọ́ nì, Jerusalemu titun nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, ti a mura silẹ bi iyawo ti a ṣe lọṣọ́ fun ọkọ rẹ̀. Mo si gbọ́ ohùn nla kan lati ori itẹ́ nì wá, nwipe, Kiyesi i, agọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mã ba wọn gbé, nwọn o si mã jẹ enia rẹ̀, ati Ọlọrun tikararẹ̀ yio wà pẹlu wọn, yio si mã jẹ Ọlọrun wọn. Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn; kì yio si si ikú mọ́, tabi ọfọ, tabi ẹkún, bẹ̃ni ki yio si irora mọ́: nitoripe ohun atijọ ti kọja lọ. Ẹniti o joko lori itẹ́ nì si wipe, Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtún. O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀: nitori ọ̀rọ wọnyi ododo ati otitọ ni nwọn. O si wi fun mi pe, O pari. Emi ni Alfa ati Omega, ipilẹṣẹ ati opin. Emi ó si fi omi fun ẹniti ongbẹ ngbẹ lati orisun omi ìye lọfẹ̃. Ẹniti o ba ṣẹgun ni yio jogún nkan wọnyi; emi o si mã jẹ Ọlọrun rẹ̀, on o si mã jẹ ọmọ mi. Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè, ati oṣó, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ní ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji. Ọkan ninu awọn angẹli meje nì, ti nwọn ni ìgo meje nì, ti o kún fun iyọnu meje ikẹhin si wá, o si ba mi sọ̀rọ wipe, Wá nihin, emi o fi iyawo, aya Ọdọ-Agutan, hàn ọ. O si mu mi lọ ninu Ẹmí si òke nla kan ti o si ga, o si fi ilu nì hàn mi, Jerusalemu mimọ́, ti nti ọrun sọkalẹ lati ọdọ Ọlọrun wá, Ti o ni ogo Ọlọrun: imọlẹ rẹ̀ si dabi okuta iyebiye gidigidi, ani bi okuta jasperi, o mọ́ bi kristali; O si ni odi nla ati giga, o si ni ẹnubode mejila, ati ni awọn ẹnubode na angẹli mejila ati orukọ ti a kọ sara wọn ti iṣe orukọ awọn ẹ̀ya mejila ti awọn ọmọ Israeli: Ni ìha ìla-õrùn ẹnubode mẹta; ni ìha ariwa ẹnubode mẹta; ni ìha gusù ẹnubode mẹta; ati ni ìha ìwọ-õrùn ẹnubode mẹta. Odi ilu na si ni ipilẹ mejila, ati lori wọn orukọ awọn Aposteli mejila ti Ọdọ-Agutan. Ẹniti o si mba mi sọ̀rọ ni ifefe wura kan fun iwọn lati fi wọ̀n ilu na ati awọn ẹnubode rẹ̀, ati odi rẹ̀. Ilu na si lelẹ ni ibú mẹrin li ọgbọgba, gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ si dọgba: o si fi ifefe nì wọ̀n ilu na, o jẹ ẹgbata oṣuwọn furlongi: gigùn rẹ̀ ati ibú rẹ̀ ati gìga rẹ̀ si dọ́gba. O si wọ̀n odi rẹ̀, o jẹ ogoje igbọnwọ le mẹrin, gẹgẹ bi oṣuwọn enia, eyini ni, ti angẹli na. Ohun ti a sì fi mọ odi na ni jasperi: ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí ti o mọ́ kedere. A fi onirũru okuta iyebiye ṣe ipilẹ ogiri ilu na lọ́ṣọ. Ipilẹ ikini jẹ jasperi; ekeji, safiru; ẹkẹta, kalkedoni; ẹkẹrin, smaragdu: Ẹkarun, sardoniki; ẹkẹfa, sardiu; ekeje, krisoliti; ẹkẹjọ berili; ẹkẹsan, topasi; ẹkẹwa, krisoprasu; ẹkọkanla, hiakinti; ekejila, ametisti. Ẹnubode mejejila jẹ perli mejila: olukuluku ẹnubode jẹ perli kan; ọ̀na igboro ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí didán. Emi kò si ri tẹmpili ninu rẹ̀: nitoripe Oluwa Ọlọrun Olodumare ni tẹmpili rẹ̀, ati Ọdọ-Agutan. Ilu na kò si ni iwá õrùn, tabi oṣupa, lati mã tan imọlẹ si i: nitoripe ogo Ọlọrun li o ntàn imọlẹ si i, Ọdọ-Agutan si ni fitila rẹ̀. Awọn orilẹ-ède yio si mã rìn nipa imọlẹ rẹ̀: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wá sinu rẹ̀. A kì yio si sé awọn ẹnubode rẹ̀ rara li ọsán: nitori kì yio si oru nibẹ̀. Nwọn o si ma mu ogo ati ọlá awọn orilẹ-ède wá sinu rẹ̀. Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.

Ifi 21:1-27 Yoruba Bible (YCE)

Mo rí ọ̀run titun ati ayé titun, ayé ti àkọ́kọ́ ti kọjá lọ. Òkun kò sì sí mọ́. Lẹ́yìn náà mo rí ìlú mímọ́ náà, Jerusalẹmu titun, tí ó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sọ̀kalẹ̀ láti òkè wá. A ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ bí ìgbà tí a bá ṣe iyawo lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn; yóo nu gbogbo omijé nù ní ojú wọn. Kò ní sí ikú mọ́, tabi ọ̀fọ̀ tabi ẹkún tabi ìrora. Nítorí àwọn ohun ti àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà sọ pé, “Mò ń sọ ohun gbogbo di titun.” Ó ní, “Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí òdodo ọ̀rọ̀ ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí.” Ó ní, “Ó parí! Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin. N óo fún ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ ní omi mu láti inú kànga omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. Ẹni tí ó bá ṣẹgun ni yóo jogún nǹkan wọnyi. N óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ̀, òun náà yóo sì máa jẹ́ ọmọ mi. Ṣugbọn àwọn ojo, àwọn alaigbagbọ, àwọn ẹlẹ́gbin, àwọn apànìyàn, àwọn àgbèrè, àwọn oṣó, àwọn abọ̀rìṣà, ati gbogbo àwọn èké ni yóo ní ìpín wọn ninu adágún iná tí ń jó, tí a fi imí-ọjọ́ dá. Èyí ni ikú keji.” Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí ó mú àwo meje lọ́wọ́, tí ìparun ìkẹyìn meje wà ninu wọn, ó wá bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní “Wá, n óo fi iyawo Ọ̀dọ́ Aguntan hàn ọ́.” Ó bá gbé mi ninu ẹ̀mí lọ sí orí òkè ńlá kan tí ó ga, ó fi Jerusalẹmu ìlú mímọ́ náà hàn mí, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ògo Ọlọrun ń tàn lára rẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye. Ẹwà rẹ̀ dàbí ti òkúta iyebíye tí ó mọ́lẹ̀ gaara. Odi ìlú náà nípọn, ó sì ga. Ó ní ìlẹ̀kùn mejila, àwọn angẹli mejila wà níbi àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. A kọ àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli mejila sí ara àwọn ìlẹ̀kùn mejila náà. Ìlẹ̀kùn mẹta wà ní ìhà ìlà oòrùn, mẹta wà ní ìhà àríwá, mẹta wà ni ìhà gúsù, mẹta wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn. Odi ìlú náà ní ìpìlẹ̀ mejila. Orúkọ mejila ti àwọn aposteli mejila ti Ọ̀dọ́ Aguntan wà lára wọn. Ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ mú ọ̀pá ìwọnlẹ̀ wúrà lọ́wọ́ láti fi wọn ìlú náà ati àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, ati odi rẹ̀. Igun mẹrẹẹrin ìlú náà dọ́gba, bákan náà ni gígùn rẹ̀ ati ìbú rẹ̀. Ó fi ọ̀pá ìwọnlẹ̀ náà wọn ìlú náà. Bákan náà ni gígùn rẹ̀, ati ìbú rẹ̀, ati gíga rẹ̀. Ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹjọ (1500) ibùsọ̀. Ó wá wọn odi rẹ̀, ó ga tó igba ẹsẹ̀ ó lé ogún (220) gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n eniyan tí angẹli náà ń lò. Òkúta iyebíye ni wọ́n fi mọ odi náà. Wúrà ni gbogbo ìlú náà tí ó mọ́ gaara bíi dígí. Òkúta iyebíye oríṣìíríṣìí ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ odi ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ kinni, òkúta iyebíye oríṣìí kan, ekeji oríṣìí mìíràn, ẹkẹta oríṣìí mìíràn, ẹkẹrin, bẹ́ẹ̀; ẹkarun-un, bẹ́ẹ̀; ẹkẹfa, bẹ́ẹ̀, ekeje bẹ́ẹ̀, ẹkẹjọ, bẹ́ẹ̀, ẹkẹsan-an, bẹ́ẹ̀, ẹkẹwaa, bẹ́ẹ̀, ikọkanla bẹ́ẹ̀, ekejila náà, bẹ́ẹ̀. Òkúta tí ó dàbí ìlẹ̀kẹ̀ ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn mejeejila ìlú náà; ẹyọ òkúta kọ̀ọ̀kan ni wọ́n fi gbẹ́ ìlẹ̀kùn kọ̀ọ̀kan. Wúrà ni wọ́n yọ́ sí títì ìlú náà. Ó mọ́ gaara bíi dígí. N kò rí Tẹmpili ninu ìlú náà. Nítorí Oluwa Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ni Tẹmpili ibẹ̀. Ìlú náà kò nílò ìmọ́lẹ̀ oòrùn tabi ti òṣùpá, nítorí pé ògo Ọlọrun ni ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí i; Ọ̀dọ́ Aguntan ni àtùpà ibẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa rìn ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn ọba ilé-ayé yóo mú ọlá wọn wá sinu rẹ̀. Wọn kò ní ti àwọn ìlẹ̀kùn ìlú náà ní gbogbo ọ̀sán; òru kò sì ní sí níbẹ̀. Wọn yóo mú ẹwà ati ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sí inú rẹ̀. Ohun ìdọ̀tí kan kò ní wọ inú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń ṣe ohun ẹ̀gbin tabi èké kò ní wọ ibẹ̀. Àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Aguntan nìkan ni yóo wọ ibẹ̀.

Ifi 21:1-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan: nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; Òkun kò sì ṣí mọ́. Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerusalẹmu tuntun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn. Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.” Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.” Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi. Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.” Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje, tí wọ́n ni ago méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-àgùntàn hàn ọ́.” Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fi ìlú náà hàn mi, Jerusalẹmu mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Tí ó ní ògo Ọlọ́run: ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasperi, ó mọ́ bí Kirisitali; Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu ibodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu ibodè náà angẹli méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Israẹli; Ní ìhà ìlà-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà gúúsù ẹnu ibodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta. Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Aposteli méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn. Ẹni tí o sì ń bá mi sọ̀rọ̀ ní ọ̀pá-ìwọ̀n wúrà kan láti fi wọn ìlú náà àti àwọn ẹnu ibodè rẹ̀, àti odi rẹ̀. Ìlú náà sì wà ní ibú mẹ́rin lọ́gbọọgba, gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀ sì dọ́gba: ó sì fi ọ̀pá-ìwọ̀n náà wọn ìlú náà wò, ó jẹ ẹgbàafà ibùsọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìbú rẹ̀, àti gíga rẹ̀ sì dọ́gba. Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ́ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí angẹli náà. A sì fi jasperi mọ odi ìlú náà. Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere. A fi onírúurú òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ èkínní jẹ́ jasperi; èkejì, safiru; ẹ̀kẹta, kalkedoni ẹ̀kẹrin, emeradi, ẹ̀karùnún, sardoniki; ẹ̀kẹfà, kaneliani; èkeje, krisoliti; ẹ̀kẹjọ, bereli; ẹ̀kẹsànán, topasi; ẹ̀kẹwàá, krisoprasu; ẹ̀kọkànlá, jakiniti; èkejìlá, ametisiti. Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ pearli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán. Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀: nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn. Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i: nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀: àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀. A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu ibodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀. Wọ́n ó sì máa mú ògo àti ọlá àwọn orílẹ̀-èdè wá sínú rẹ̀. Ohun aláìmọ́ kan ki yóò sì wọ inú rẹ̀ rárá, tàbí ohun tí ń ṣiṣẹ́ ìríra àti èké; bí kò ṣe àwọn tí a kọ sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-àgùntàn.