Ẹkẹta si tú ìgo tirẹ̀ sinu odò, ati si orisun awọn omi; nwọn si di ẹ̀jẹ. Mo si gbọ́ angẹli ti omi nì wipe, Olododo ni Iwọ Ẹni-Mimọ́, ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, nitoriti iwọ ṣe idajọ bayi. Nitoriti nwọn ti ta ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́ ati ti awọn woli silẹ, iwọ si fi ẹ̀jẹ fun wọn mu; eyiyi li o yẹ wọn. Mo si gbọ́ pẹpẹ nke wipe, Bẹ̃ni, Oluwa Ọlọrun Olodumare, otitọ ati ododo ni idajọ rẹ.
Kà Ifi 16
Feti si Ifi 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ifi 16:4-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò