Angẹli keje si fun ipè; a si gbọ́ ohùn nla lati ọrun wá, wipe, Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; on o si jọba lai ati lailai. Awọn àgba mẹrinlelogun nì ti nwọn joko niwaju Ọlọrun lori ítẹ wọn, dojubolẹ, nwọn si sìn Ọlọrun, Wipe, Awa fi ọpẹ́ fun ọ, Oluwa Ọlọrun, Olodumare, ti mbẹ, ti o si ti wà, ti o si ma bọ̀; nitoriti iwọ ti gbà agbara nla rẹ, iwọ si ti jọba. Inu si bi awọn orilẹ-ède, ibinu rẹ si de, ati ìgba lati dá awọn okú lẹjọ, ati lati fi ere fun awọn iranṣẹ rẹ woli ati awọn enia mimọ́ ati awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ, ati ẹni kekere ati ẹni nla; ati lati run awọn ti npa aiye run. A si ṣí tẹmpili Ọlọrun silẹ li ọrun, a si ri apoti majẹmu ninu tẹmpili rẹ̀: mànamána si kọ, a si gbọ ohùn, ãrá si san, ìṣẹlẹ si ṣẹ̀, yinyín nla si bọ.
Kà Ifi 11
Feti si Ifi 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ifi 11:15-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò