ÌFIHÀN 11:15-19

ÌFIHÀN 11:15-19 YCE

Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.” Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọrun bá dojúbolẹ̀, wọ́n júbà Ọlọrun. Wọ́n ní, “A fi ìyìn fún ọ, Oluwa, Ọlọrun Olodumare, ẹni tí ó wà, tí ó ti wà, nítorí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ń jọba. Inú àwọn orílẹ̀-èdè ru, ṣugbọn àkókò ibinu rẹ dé, ó tó àkókò láti ṣe ìdájọ́ àwọn òkú, ati láti fi èrè fún àwọn iranṣẹ rẹ, àwọn wolii, àwọn eniyan rẹ, ati àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ, ìbáà ṣe àwọn mẹ̀kúnnù tabi àwọn eniyan ńláńlá. Àkókò dé láti pa àwọn tí ó ń ba ayé jẹ́ run.” Tẹmpili Ọlọrun ti ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run, tí a fi lè rí àpótí majẹmu ninu rẹ̀. Mànàmáná wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ, ààrá ń sán, ilẹ̀ ń mì tìtì; yìnyín sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ sílẹ̀.