O. Daf 69

69
Igbe fún Ìrànlọ́wọ́
1ỌLỌRUN, gbà mi; nitoriti omi wọnni wọ̀ inu lọ si ọkàn mi.
2Emi rì ninu irà jijin, nibiti ibuduro kò si, emi de inu omi jijin wọnni, nibiti iṣan-omi ṣàn bò mi lori.
3Agara ẹkun mi da mi: ọfun mi gbẹ: oju kún mi nigbati emi duro de Ọlọrun mi.
4Awọn ti o korira mi lainidi jù irun ori mi lọ: awọn ti nṣe ọta mi laiṣẹ, ti iba pa mi run, nwọn lagbara: nigbana ni mo san ohun ti emi kò mu.
5Ọlọrun, iwọ mọ̀ wère mi, ẹ̀ṣẹ mi kò si lumọ kuro loju rẹ.
6Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, máṣe jẹ ki oju ki o tì awọn ti o duro de ọ nitori mi: máṣe jẹ ki awọn ti nwá ọ ki o damu nitori mi, Ọlọrun Israeli.
7Nitoripe nitori tirẹ li emi ṣe nrù ẹ̀gan; itiju ti bo mi loju.
8Emi di àjeji si awọn arakunrin mi, ati alejo si awọn ọmọ iya mi.
9Nitori ti itara ile rẹ ti jẹ mi tan; ati ẹ̀gan awọn ti o gàn ọ, ṣubu lù mi.
10Nigbati mo sọkun, ti mo si nfi àwẹ jẹ ara mi ni ìya, eyi na si di ẹ̀gan mi.
11Emi fi aṣọ ọ̀fọ sẹ aṣọ mi pẹlu: mo si di ẹni-owe fun wọn.
12Awọn ti o joko li ẹnu-bode nsọ̀rọ si mi; emi si di orin awọn ọmuti.
13Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, iwọ li emi ngbadura mi si, Oluwa, ni igba itẹwọgba: Ọlọrun, ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ da mi lohùn, ninu otitọ igbala rẹ.
14Yọ mi kuro ninu ẹrẹ̀, má si ṣe jẹ ki emi ki o rì: gbigbà ni ki a gbà mi lọwọ awọn ti o korira mi, ati ninu omi jijìn wọnni.
15Máṣe jẹ ki kikún-omi ki o bò mi mọlẹ, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki ọgbun ki o gbé mi mì, ki o má si ṣe jẹ ki iho ki o pa ẹnu rẹ̀ de mọ́ mi.
16Oluwa, da mi lohùn; nitori ti iṣeun ifẹ rẹ dara, yipada si mi gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ irọnu ãnu rẹ.
17Ki o má si ṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lara iranṣẹ rẹ: emi sa wà ninu ipọnju; yara, da mi lohùn.
18Sunmọ ọkàn mi, si rà a pada: gbà mi nitori awọn ọta mi.
19Iwọ ti mọ̀ ẹ̀gan mi ati ìtiju mi, ati alailọla mi: gbogbo awọn ọta mi li o wà niwaju rẹ.
20Ẹgan ti bà mi ni inu jẹ; emi si kún fun ikãnu: emi si woye fun ẹniti yio ṣãnu fun mi, ṣugbọn kò si; ati fun awọn olutunu, emi kò si ri ẹnikan.
21Nwọn fi orõro fun mi pẹlu li ohun jijẹ mi; ati li ongbẹ mi nwọn fun mi li ọti kikan ni mimu.
22Jẹ ki tabili wọn ki o di ikẹkun niwaju wọn: fun awọn ti o wà li alafia, ki o si di okùn didẹ.
23Jẹ ki oju wọn ki o ṣú, ki nwọn ki o má riran, ki o si ma mu ẹgbẹ́ wọn gbọn nigbagbogbo.
24Dà irunu rẹ si wọn lori, si jẹ ki ikannu ibinu rẹ ki o le wọn ba.
25Jẹ ki ibujoko wọn ki o di ahoro; ki ẹnikẹni ki o máṣe gbe inu agọ wọn.
26Nitori ti nwọn nṣe inunibini si ẹniti iwọ ti lù; nwọn si nsọ̀rọ ibinujẹ ti awọn ti iwọ ti ṣá li ọgbẹ.
27Fi ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ wọn: ki o má si ṣe jẹ ki nwọn ki o wá sinu ododo rẹ.
28Nù wọn kuro ninu iwe awọn alãye, ki a má si kọwe wọn pẹlu awọn olododo.
29Ṣugbọn talaka ati ẹni-ikãnu li emi, Ọlọrun jẹ ki igbala rẹ ki o gbé mi leke.
30Emi o fi orin yìn orukọ Ọlọrun, emi o si fi ọpẹ gbé orukọ rẹ̀ ga.
31Eyi pẹlu ni yio wù Oluwa jù ọda-malu tabi akọ-malu lọ ti o ni iwo ati bàta ẹsẹ.
32Awọn onirẹlẹ yio ri eyi, inu wọn o si dùn: ọkàn ẹnyin ti nwá Ọlọrun yio si wà lãye.
33Nitoriti Oluwa gbohùn awọn talaka, kò si fi oju pa awọn ara tubu rẹ̀ rẹ́.
34Jẹ ki ọrun on aiye ki o yìn i, okun ati ohun gbogbo ti nrakò ninu wọn.
35Nitoriti Ọlọrun yio gbà Sioni là, yio si kọ́ ilu Juda wọnni: ki nwọn ki o le ma gbe ibẹ, ki nwọn ki o le ma ni i ni ilẹ-ini.
36Iru-ọmọ awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ni yio ma jogun rẹ̀: awọn ti o si fẹ orukọ rẹ̀ ni yio ma gbe inu rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 69: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀