O. Daf 50

50
Ìsìn Tòótọ́
1ỌLỌRUN Olodumare, ani Oluwa li o ti sọ̀rọ, o si pè aiye lati ìla-õrun wá titi o fi de ìwọ rẹ̀.
2Lati Sioni wá, pipé ẹwà, Ọlọrun ti tan imọlẹ.
3Ọlọrun wa mbọ̀, kì yio si dakẹ; iná yio ma jó niwaju rẹ̀, ẹfufu lile yio si ma ja yi i ka kiri.
4Yio si kọ si awọn ọrun lati òke wá, ati si aiye, ki o le ma ṣe idajọ awọn enia rẹ̀.
5Kó awọn enia mimọ́ mi jọ pọ̀ si ọdọ mi: awọn ti o fi ẹbọ ba mi da majẹmu.
6Awọn ọrun yio si sọ̀rọ ododo rẹ̀: nitori Ọlọrun tikararẹ̀ li onidajọ.
7Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si sọ̀rọ; Israeli, emi o si jẹri si ọ: emi li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ.
8Emi kì yio ba ọ wi nitori ẹbọ rẹ, ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ wà niwaju mi nigbagbogbo.
9Emi kì yio mu akọ-malu lati ile rẹ jade, tabi obukọ ninu agbo-ẹran rẹ:
10Nitori gbogbo ẹran igbo ni ti emi, ati ẹrankẹran lori ẹgbẹrun òke.
11Emi mọ̀ gbogbo ẹiyẹ awọn oke nla: ati ẹranko igbẹ ni ti emi.
12Bi ebi npa mi, emi kì yio sọ fun ọ: nitori pe aiye ni ti emi, ati ẹkún inu rẹ̀.
13Emi o ha jẹ ẹran malu, tabi emi a ma mu ẹ̀jẹ ewurẹ bi?
14Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjẹ́ rẹ fun Ọga-ogo.
15Ki o si kepè mi ni ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yìn mi logo.
16Ṣugbọn Ọlọrun wi fun enia buburu pe, Kini iwọ ni ifi ṣe lati ma sọ̀rọ ilana mi, tabi ti iwọ fi nmu majẹmu mi li ẹnu rẹ?
17Wò o, iwọ sa korira ẹkọ́, iwọ si ti ṣá ọ̀rọ mi tì lẹhin rẹ.
18Nigbati iwọ ri olè, nigbana ni iwọ ba a mọ̀ ọ pọ̀, iwọ si ba awọn àgbere ṣe ajọpin.
19Iwọ fi ẹnu rẹ fun buburu, ati ahọn rẹ npete ẹ̀tan.
20Iwọ joko, iwọ si sọ̀rọ si arakunrin rẹ: iwọ mba orukọ ọmọ iya rẹ jẹ.
21Nkan wọnyi ni iwọ ṣe emi si dakẹ; iwọ ṣebi emi tilẹ dabi iru iwọ tikararẹ; emi o ba ọ wi, emi o si kà wọn li ẹsẹ-ẹsẹ ni oju rẹ.
22Njẹ rò eyi, ẹnyin ti o gbagbe Ọlọrun, ki emi ki o má ba fà nyin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ti kò si olugbala.
23Ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ iyìn, o yìn mi logo: ati ẹniti o ba mu ọ̀na ọ̀rọ rẹ̀ tọ́ li emi o fi igbala Ọlọrun hàn fun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 50: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀