O. Daf 5

5
Adura Ààbò
1FI eti si ọ̀rọ mi, Oluwa, kiyesi aroye mi.
2Fi eti si ohùn ẹkún mi, Ọba mi, ati Ọlọrun mi: nitoripe ọdọ rẹ li emi o ma gbadura si.
3Ohùn mi ni iwọ o gbọ́ li owurọ, Oluwa, li owurọ li emi o gbà adura mi si ọ, emi o si ma wòke.
4Nitori ti iwọ kì iṣe Ọlọrun ti iṣe inu-didùn si ìwa buburu: bẹ̃ni ibi kò le ba ọ gbe.
5Awọn agberaga kì yio le duro niwaju rẹ: iwọ korira gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ.
6Iwọ o pa awọn ti nṣe eke run; Oluwa yio korira awọn ẹni-ẹ̀jẹ ati ẹni-ẹ̀tan.
7Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o wá sinu ile rẹ li ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ: ninu ẹ̀ru rẹ li emi o tẹriba si iha tempili mimọ́ rẹ.
8Tọ́ mi, Oluwa, ninu ododo rẹ, nitori awọn ọta mi: mu ọ̀na rẹ tọ́ tàra niwaju mi.
9Nitori ti otitọ kan kò si li ẹnu ẹnikẹni wọn; ikakika ni iha inu wọn; isa-okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi npọ́nni.
10Iwọ da wọn lẹbi, Ọlọrun; ki nwọn ki o ti ipa ìmọ ara wọn ṣubu; já wọn kuro nitori ọ̀pọlọpọ irekọja wọn; nitori ti nwọn ti ṣọ̀tẹ si ọ.
11Nigbana ni gbogbo awọn ti ngbẹkẹle ọ yio yọ̀; lai nwọn o ma ho fun ayọ̀, nitoriti iwọ dabobo wọn: ati awọn ti o fẹ orukọ rẹ pẹlu yio ma yọ̀ ninu rẹ.
12Nitori iwọ, Oluwa, ni yio bukún fun olododo; oju-rere ni iwọ o fi yi i ka bi asà.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa